Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria, Goodluck Ebele Jonathan ti ṣabẹwo si Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu lati kii ku oriire fun bo ṣe jawe olubori ninu eto idibo apapọ ọdun 2023, to si tun ti bẹrẹ iṣẹ lakọtun.
Oni, Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni Jonatha ṣabẹwo si Tinubu nile agbara orileede yii, iyẹn Aso-Rock to wa niluu Abuja.
Bo tilẹ jẹ pe bi Jonathan ṣe wọle, niṣe loun pẹlu Tinubu lọ ṣe ipade ikọkọ fun bi iṣẹju meloo kan, ko to di pe wọn jade pada lati ya fọto.
No comments:
Post a Comment