Gbogbo eto lo ti pari patapata bayii, fun bọọsi ọfẹ lati maa gbe gbogbo awọn akẹkọọ patapata kaakiri ipinlẹ Kwara lọ sile ẹkọ wọn, ti yoo si tun maa da wọn pada sile wọn lọfẹẹ.
Eto yii ni Gomina ipinlẹ naa, Malaamu AbdulRahman AbdulRazaq ṣagbekalẹ rẹ lati fi mu irọrun ba gbogbo awọn akẹkọọ patapata nipa irin ajo wọn sile-ẹkọ tonikaluku wọn n lọ.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, ọsẹ yii ni eto ọhun yoo bẹrẹ ni pẹrẹu, iyẹn ọla.
Yatọ si awọn akẹkọọ ti awọn bọọsi naa yoo maa gbe, a tun gbọ pe gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba patapata kaakiri ipinlẹ naa ni wọn yoo tun jẹ ninu anfaani ara-ọtọ yii.
Igbesẹ yii lo waye lori bi ijọba apapọ ṣe yọ owo ori iranwọ epo kuro, to mu kowo epo rọbii lọ soke si ẹẹdẹgbẹta naira.
Lati ori awọn akẹkọọ ile-ẹkọ alakọbẹrẹ titi de girama, to fi mọ awọn ile-ẹkọ giga patapata lai yọ ẹnikẹni silẹ lanfaani yii wa fun, ati pe awọn ikorita patapata ni awọn bọọsi nla-nla yii yoo ti lọ maa gbe wọn laarọ, ti yoo si tun maa da wọn pada nigba ti wọn ba pari lọsan ati ni irọlẹ.
Ṣaaju akoko yii ni ijọba Kwara ti din lilọ si ibiṣẹ awọn oṣiṣẹ ku lati ọjọ marun-un si ọjọ mẹta pere, eyi to n mu k'awọn araalu maa dupẹ lọwọ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq to n mu awọn ileri rẹ ṣẹ.
No comments:
Post a Comment