Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ ti ṣabẹwo si Aarẹ ana lorileede Naijiria, Muhammadu Buhari nile rẹ to wa niluu Daura, ipinlẹ Katsina.
Abiọdun lo ṣabẹwo naa pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ lati kii fun iṣẹ takuntakun to ṣe fun ọdun mẹjọ gbako lorileede Naijiria.
Nibẹ ni wọn tun ti lọ fi ẹmi imoore han si Buhari, ti wọn si dupẹ gidigidi fun atilẹyin rẹ.
Gomina Abiọdun lo fi soju opo ayelujara rẹ l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii pẹlu awọn fọto abẹwo naa.
No comments:
Post a Comment