Olori ile igbimọ aṣofin kekere lorileede Naijiria tẹlẹ, Ọnarebu Fẹmi Gbajabiamila la gbọ pe yoo kọwe f'ipo rẹ silẹ lonii nile igbimọ aṣoju-ṣofin naa.
Gbajabiamila ni Aarẹ Tinubu yan gẹgẹ bi olori awọn oṣiṣẹ aarẹ lọjọ keji, oṣu kẹfa, ọdun 2023.
Bẹ o ba gbagbe, ninu eto idibo to waye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu keji, ọdun yii ni wọn tun dibo yan Gbajabiamila lati ṣoju ẹkun Surulere kin-in-ni nile igbimọ aṣoju-ṣofin naa, eyii si ni yoo jẹ igbakẹfa ti lọ.
Latigba ti Aarẹ Tinubu si ti yan an ni oriṣiriṣi awuyewuye ti n waye lori bi Gbajabiamila yoo ṣe ṣe e, iyẹn lati di aṣoju-ṣofin ati lati maa ṣiṣẹ gẹgẹ bi olori awọn oṣiṣẹ aarẹ.
Bakan naa la tun gbọ pe lẹta ti Gbajabiamila yoo fi kalẹ yii ni yoo fun ajọ eleto idibo Independent National Electoral Commission, INEC, lati ṣe atundi ibo miran.
No comments:
Post a Comment