Alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele ti sọ pe eto ọrọ aje orileede Naijiria nilo adura rẹpẹtẹ lati bọ kuro lọwọ ilakaka to tun ṣẹṣẹ bọ si yii.
Wolii Ayọdele sọ pe igbesẹ ti banki apapọ Naijiria ṣẹṣẹ gbe kalẹ lati gbe owo naira soke kii ṣe ipinnu to dara lati mu ilọsiwaju ba eto ọrọ aje Naijiria rara, bi ko ṣe pe ipalara ni yoo jẹ.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin Wolii Ayọdele, Ọgbẹni Oluwatosin Ọṣhọ gbe jade laipẹ yii lo ti jẹ ko di mimọ pe pẹlu igbesẹ yii, gbogbo ireti banki apapọ, CBN ni yoo ja sofo nitori eto ọrọ aje Naijiria ko nii ṣe daadaa.
O ni igbesẹ to lodi ni Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu gbe, eyi ti yoo pada ran eto ọrọ aje lo sinu wahala ati idaamu, ati pe gbogbo owo ọja ni yoo tun lọ soke.
Wolii Ayọdele wa rọ Aarẹ Tinubu lati wa ọna abayọ miran ti yoo fi tan iṣoro Naijiria, bi bẹẹ kọ, awọn ọmọ Naijiria yoo tun maa jiya sii ni.
No comments:
Post a Comment