Gbajumọ oṣerebinrin nni, Iyabọ Ojo ti sọ ọ di mimọ nita gbangba wi pe oun ko jẹ ijọba ipinlẹ Ekoo lowo ori kankan, ati pe ẹsun ti kii ṣe toun ni wọn fi kan oun.
Ijọba ipinlẹ Ekoo ni wọn fẹsun kan Iyabọ Ojo wi pe o jẹ gbese owo ori miliọnu mejidinlogun ataabọ naira (₦18, 640, 092.00), ati pe o gbọdọ san owo naa laaarin ọjọ meje pere.
Obinrin ọlọmọ meji naa sọ pe ki Sanwo-Olu ati ijọba ipinlẹ Ekoo ṣalaye ẹsun gbese ti wọn fi kan oun, ko to di pe wọn gbe igbesẹ lati fẹsun kan oun.
Ninu ọrọ rẹ, o loun ko jẹ owo kankan nitori pe gbogbo owo to yẹ koun san lori ile ati ileeṣẹ toun ti n taja, loun n san deedee.
O ni boun ṣe n san owo ori ati awọn ẹtọ fun ìjọba ni gbogbo igba, ko ye oun rara bi ijọba tun ṣe sọ pe oun jẹ owo to din diẹ ni ogun miliọnu naira, ti wọn si loun gbọdọ san an laaarin ọjọ meje pere.
"Ẹyin eeyan yii sọ pe ki n wa laipẹ yii, mo yọju sii yin, ẹ ni ki n ṣalaye, ki n si sọ iye owo to n wọle fun mi, ti mo si ṣe pẹlu oludamọran mi lori ọrọ owo ori, ṣugbọn sibẹ, ẹ ko fesi si lẹta mi, nitori pe ẹ fẹ ki n san owo ti yoo ga mi lara, eyi ti mi o ni. "Bawo lẹyin eeyan yii ṣe panupọ wi pe aduro owo nla yii ni mo jẹ?
"Mi o mọ iye ti ẹ ro pe mo n gba. Eyi to mu ki awọn ikọ yin sọ pe iye ti mo jẹ niyẹn.
"Ki lẹyin eeyan yii tiẹ ti ṣe fun mi ri gẹgẹ bi ijọba? KO SII!!! Funra mi ni mo n da awọn ọmọ mi tọ, ati awon miran, pẹlu ara mi, ti ko si ṣẹyin ijọba. Sibẹ, ẹ wa n fọkan balẹ lati ko ire oda ọgọrun-un nibi ti ẹ ko ṣe si.
"Mo ti ṣiṣẹ, mo si tun n ṣiṣẹ takuntakun lai sinmi lati gbe lorileede yii lai si iranlọwọ ijọba nibẹ. Ṣugbọn sibẹ, ẹ jokoo ni kọọrọ ọfiisi yin lati gbe iru gbese yii kọ mi lọrun. Ko tìẹ wa si nnkan to n ṣiṣẹ daadaa mọ lorileede yii, sibẹ ẹ wa ro pe ẹ fẹẹ gba nibi ti ẹ ko ṣe si.
"Nigba ti ẹ ti wa a pinnu. Ẹ le fi idunnu wa lati tilẹkun ileeṣẹ mi, ki ẹ si gbe mi, ki ẹ ti mi mọle, tabi ki ẹ pa mi nitori pe ko kan mi. Gbogbo wa la maa ku lọjọ kan, mi o si bẹru ohun ti yoo jẹ ipin ati ireti gbogbo eeyan. Ohun ti mi o ni, mi o le fi silẹ."
No comments:
Post a Comment