Burukutu ti mo mu lo pa mi sodi, ẹ ṣaanu mi - Baba agbalagba to fipa ja ibale ọmọ ọdun meje sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 14, 2023

Burukutu ti mo mu lo pa mi sodi, ẹ ṣaanu mi - Baba agbalagba to fipa ja ibale ọmọ ọdun meje sọrọ


Ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogoji kan, Sadiq Ahmẹd ti wọn lo fipa ja ibale ọmọdebinrin, ọmọ ọdun meje niluu Adamawa ti sọ pe kii ṣe ẹjọ oun, bi ko ṣe ọti Burukutu toun mu, eyi to pada ṣe akoba foun.
 
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni Ahmẹd f'ipa ba ọmọdebinrin naa laṣepọ karakara, to si pada jẹwọ nigba t'awọn ọlọpaa n foju rẹ han f'awọn akọroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ana.
 
Ahmẹd ni ọti Burukutu toun mu lọjọ naa lo pa oun sodi, toun ko si mọ nnkan toun n ṣe lasiko toun lọ sipa ba ọmọ naa laṣepọ.
 
O loun ko ni ọti meji to kọja buruku, to si loun kabamọ pe iru iwa bẹẹ tọwọ oun ṣẹlẹ, ẹyi to loun ko ṣe ri laye.
 
Agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Suleiman Yahaya Nguroje, lo ṣalaye pe baba ọmọ naa lo wa fi ẹjọ sun, t'awọn fi lọ gbe e
 
O ni naira mẹwaa pere ni Ahmẹd fun ọmọ naa lẹyin to huwa buruku ọhun tan, ati pe asiko t'awọn ko si nile lo wọle tọ ọmọ naa lati ba a laṣepọ.
 
Nguroje ti wa sọ pe ọga awọn Afọlabi Babatọla ti ṣeleri wi pe idajọ ododo yoo waye lori iṣẹlẹ ọhun, nitori pe Ahmẹd yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI