Banki agbaye ti fidi rẹ mulẹ wi pe awọn ti ṣetan lati ya ijọba orileede Naijiria ni owo to to ẹẹdẹgbẹta miliọnu owo dọla fun irolagbara awọn obinrin.
Ninu atẹjade ti Banki agbaye naa fi sita laipẹ yii, wọn ni lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 2018 ni awọ ti kọkọ buwọ lu ẹyawo naa, ati pe ọgọrun miliọnu owo dọla fun eto ilọsiwaju awọn obinrin.
Siwaju sii ni wọn jẹ ko di mimọ pe awọn yoo tubọ ma dide iranlọwọ fun eto awọn obinrin lorileede Naijiria lapapọ.
Eyi ni yoo jẹ ẹyawo keji ti banki agbaye yoo maa bu ọwọ lu latigba ti Aarẹ Tinubu ti de ori ipo.
No comments:
Post a Comment