Ileeṣẹ eleto aabo Amọtẹkun, ẹka t'ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Lukman Oyelade, lori ẹsun wi pe o n ko ibọn kaakiri lọna aitọ.
Awọn ara adugbo kan ti wọn pe ni Ajijọla Anọbi to wa niluu Ẹdẹ, ipinlẹ naa la gbọ pe wọn ta ileeṣẹ Amọtẹkun lolobo, wi pe awọn kofiri ọkunrin kan pẹlu ibọn.
Ibọn nla ẹlẹnu meji, ibọn nla ẹlẹnu meje, ibọn kekere ẹlẹnu mẹrin ati awọn oriṣiriṣi ibọn miran la gbọ pe wọn gba lọwọ Lukman ni kete tọwọ palaba rẹ segi.
Ọga agba Amọtẹkun nipinlẹ naa, Ajagunfẹyinti Bashir Adewinmbi to fidi iroyin ọhun mulẹ jẹ ko di mimọ pe aarin oru ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii lọwọ palaba Lukman segi, lẹyin t'awọn kan wa fẹjọ rẹ sun.
Adewinmbi sọ pe Lukman ti jẹwọ pe oun loun ni awọ ibọn naa, ati pe oriṣiriṣi iwa ọdaran loun ti kopa ninu ẹ kaakiri ipinlẹ Ọṣun lai mọ pe aṣiri maa pada tu.
O ni Lukman tun ti jẹwọ pe ẹnikan to n jẹ Taye Fumble, ogbologbo gbajumọ tọọgi niluu Ẹdẹ loun maa n tọju awọn ibọn naa si lọwọ
Siwaju sii lo sọ pe awọn yoo fa Lukman le awọn ọlọpaa lọwọ lati tẹsiwaju iwadii wọn lori ẹ.
No comments:
Post a Comment