Ọjọ buruku, eṣu gbomimu lọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, to kọja yii jẹ nipinlẹ Ogun, pẹlu bi awọn ojiṣẹ Ọlọrun mẹta ṣe padanu ẹmi wọn sinu ijamba mọto lojo ọna marosẹ Abẹokuta si Ṣagamu.
Nnkan bi aago mẹwaa ku iṣẹju mẹrindinlogun aarọ la gbọ pe ijamba naa waye.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ ajọ ẹṣọ oju popona n'ipinlẹ Ogun, Traffic Compliance and Enforcement (TRACE) Corps, Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi ṣe ṣalaye, o sọ pe niṣe ni awakọ naa gbagbe sun lọ lori ere asapajude, to si ṣe bẹẹ sọ ijanu rẹ nu.
Akinbiyi sọ pe ẹpa ko boro mọ nigba ti awakọ ọhun yoo fi taji lati oju oorun to wa, to si mu ki mọto wọn fori sọ tirela toun naa n lọ loju ọna ọhun, niwaju ile-ẹkọ Day Waterman College.
Inu mọto KIA RIO alawọ dudu, ti nọmba idanimọ rẹ jẹAKD 827 DV, eyi to jẹ ti ọkan lara awọn ojiṣẹ Ọlọrun naa ni gbogbo wọn wa lasiko iṣẹlẹ yii.
Siwaju sii ni Akinbiyi fi to wa leti pe niṣe mọto naa fo kuro lọna rẹ, to si ba irin ina aarin meji naa jẹ, ko to lọ kọlu tirela Sino Truck to ko simẹnti, eyi ti nọmba idanimọ rẹ jẹ WDL 466 XA.
Awọn meje la gbọ pe wọn wa kagbako ninu ijamba ọkọ naa, ti mẹta si dakẹ loju ẹsẹ, eyi ti awọn meji farapa yannayanna, ṣugbọn ti ori ko awọn meji miran yọ.
Ọsibitu jẹnẹra to wa ni Ijaye niluu Abẹokuta la gbọ pe awọn eleto aabo sare gbe awọn to farapa lọ fun itọju, ti wọn si ko awọn oku naa lọ mọṣuari.
Akinbiyi lo jẹ ka mọ pe ibi adura itusilẹ l'awọn ojiṣẹ Ọlọrun naa ti n bọ niluu Oke-Iragbiji, ipinlẹ Ọṣun lọjọ naa, ko to di pe wọn pade iku ojiji yii.
No comments:
Post a Comment