Atiku, PDP l'awọn ko ba Tinubu ṣ'ẹjọ kankan mọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 20, 2023

Atiku, PDP l'awọn ko ba Tinubu ṣ'ẹjọ kankan mọ


Oludije s'opo Aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Alaaji Atiku Abubakar ati ẹgbẹ naa ti sọ pe awọn ṣetan lati jawọ ninu ẹjọ ti wọn pe lati tako idibo to gbe Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu wọle.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii ni Atiku ati PDP l'awọn yoo jawọ kuro ninu ipẹjọ naa.
 
Amofin to lewaju awọn agbẹjọro Atiku ati PDP, Oloye Chris Uche nigba to n sọrọ ṣalaye pe awọn ti padanu lẹẹmeji, bo tilẹ jẹ pe awọn gbiyanju, ṣugbọn to lo di dandan lati pana ẹjọ ọhun.
 
“A maa f'opin si ẹjọ naa l'Ọjọbọ, Tọsidee, bo tilẹ jẹ pe oni ọjọ Iṣẹgun, tusidee lo yẹ ki ẹjọ naa d'opin, ṣugbọn ti ile-ẹjọ fun wa ni ọjọ meji sii nitori ayajọ June 12 to yẹ ki igbẹjọ yii waye.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI