Anthony ati Joy ta ọmọ ọsu kan wọn, ni wọn ba f'owo rẹ ra igbo mu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 24, 2023

Anthony ati Joy ta ọmọ ọsu kan wọn, ni wọn ba f'owo rẹ ra igbo mu


Ọrọ buruku toun tẹrin nigba tọwọ awọ oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti aṣilo oogun ati egboogi oloro n'ipinlẹ Edo, iyẹn Edo State Task Force Against Human Trafficking rọwọ to ololufẹ meji kan, Anthony Igbinogun ati Joy Umukoro lori ẹsun wi pe wọn n ta igbo.
 
Kii ṣe bi wọn n fa igbo lo n mu k'ọrọ naa maa ya awọn eeyan lẹnu, bi ko ṣe bi wọn ṣe ta ọmọ oṣu kan to pa wọn pọ lati fi owo rẹ kun okoowo igbo ti wọn n mu.
 
Anthony, ẹni ọdun mejidinlaadọta ati Joy, toun jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn ni ajọ naa foju wọn han f'awọ akọroyin niluu Benin l'ọjọ Ẹti tii ṣe Furaide, ọsẹ yii.

Nigba to n sọrọ, ọga agba l'ẹka eto iwadii ileeṣẹ naa, Abigail Ihonre sọ pe ọwọ tẹ ololufẹ meji yii pẹlu ọrẹ wọn kan, Precios James, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ buruku yii.

Abigail sọ siwaju pe Precios lo mu ẹni to ra ọmọ naa wa, to si ni miliọnu kan ataabọ le (₦1.7m) naira ni wọn ta a fun ẹni to ra a niluu Port Harcourt, ipinlẹ Rivers.

O ni iwadii awọn ti bẹrẹ lati gba ọmọ ọhun pada, ki wọn si rọwọ to ẹni to ra ọmọ.

Inu oṣu kẹrin, ọdun 2023 ti a wa yii ni Jou bimọ naa, to si lẹdi apo pọ pẹlu ọrẹkunrin rẹ lati ta ọmọ yii.

Siwaju sii lo sọ pe bi iwadii ṣe n tẹsiwaju, awọn tọwọ yii yoo foju ba ile-ẹjọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹfa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI