Agura t’ilu Gbagura, Ọba Saburee Babajide Iṣọla Bakre, Jamolu keji (Apa Kinni) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 18, 2023

Agura t’ilu Gbagura, Ọba Saburee Babajide Iṣọla Bakre, Jamolu keji (Apa Kinni)


"Maa yọ, maa yọ, ma yọ o, l’ori Olumọ,
Maa yọ, maa yọ, ma yọ o, l’ori Olumọ." 
Itiju nla lo yẹ ko jẹ fun gbogbo ọmọ ilu Ẹgba to ba sọ pe oun ko mọ orin ogo ilu Ẹgba. 

Lati kekere, ki ọmọ to o bẹrẹ si i sọrọ lo yẹ ki wọn si ti maa kọ orin ogo yii s’eti awọn ọmọ wọn, ko le di ohun ti wọn n gbe larugẹ kaakiri agbaye. Ayafi bi a ba fee parọ tan ara wa jẹ, ko ti i si ori ogo ilu kan to dun to ti ilu Ẹgba. Awọn ti wọn ki i ṣe ọmọ ilu Ẹgba gan an mọ orin yii ju awọn ti wọn jẹ ọmọ bibi ilu naa lọ.

Lara awọn opo mẹrin to tẹ ilu Ẹgba do ni Gbagura. Ko si si bi a ti fẹẹ sọ itan ilu Ẹgba, abi Abẹokuta ti a le yọ awọn Gbagura kuro ninu ẹ, ko ṣee ṣe. Balogun Ọjọọ lo ko awọn ọmọ Gbagura wọ ilu Abẹokuta. Wọn si pẹlu ba wọn bẹrẹ si i jẹ ọba n’ilu Ẹgba ni.

Gbara ti Ẹgba Ake, Ẹgba Gbagura ati Ẹgba Oke-Ọna ati Ẹgba Owu wọ ilu Abẹokuta ni wọn ti l’awọn ko ṣetan lati jẹ ọba. Nigba ti wọn si ri i pe asiko ti to fun wọn lati bẹrẹ si i jẹ ọba, asiko kan naa ni gbogbo wọn bẹrẹ si i jẹ ọba wọn, iyẹn l’ọdun 1870, yatọ si Ẹgba Oke-Ọna ti wọn l’awọn ko ti i ṣetan ni ti wọn.

Lara awọn ti itan ko le gbagbe wọn ninu awọn to fun alaafia Ẹgba lati ilu Gbagura ni Oluwọle Agbo, Balogun Ọjọọ, ẹni to fi iyawo rẹ to wa ninu oyun silẹ lati rubọ; Anọba, Balogun Ika; Dada Ojigan, to jẹ oye Aarẹ akọkọ; Oluṣẹyẹ Balogun tilu Ika; Balogun Iddo ati Efunroye Tinubu.

Ilu Ẹgba Gbagura tobi pupọ, wọn si tan kaakiri ilẹ Yoruba. Ẹrinlelogoje {144} ilu ni wọn parapọ, ti wọn n jẹ Gbagura, ṣugbọn nigba to to awọn asiko kan, ilu mejilelaadọrin (72) dide, wọn si l’awọn ko ba awọn Gbagura ṣe pọ mọ, wọn yapa lati tẹle awọn Ẹgba Oke-Ọna lọ. Lara awọn ilu to n jẹ Gbagura tẹlẹ ni Wasinmi, Iddo, Ilugun, Ilawọ, at'awọn mi in bẹẹ. Ṣugbọn Ilugun at’awọn mi in ti yapa sabẹ Oke-Ọna.

Nigba ogun, itosi odo ogun l’awọn Gbagura tẹdo si, ti wọn ti n jaye ori wọn. Agbara ti wọn ni pọ pupọ debi wi pe awọn Gbagura l’awọn Ẹgbado, Ijẹbu-Rẹmọ to fi mọ Awori kọkọ mọ, ti wọn si n ri wọn gẹgẹ bi alagbara Ẹgba.

Gbogbo ija t’awọn Egba ja naa ni ko ṣẹyin awọn Gbagura, wọn jọ jagun naa ni. Awọn ogun ti wọn ja pẹlu awọn Ijẹbu Rẹmọ l’ọdun 1832, pẹlu awọn Ibadan l’ọdun 1834, pẹlu awọn Ọta l’ọdun 1842, Ado l’oọdun 1844, Ibarapa l’ọdun 1849, Dahomey l’ọdun 1851, Ijẹbu-Ere l’odun 1851, Ijaye l’ọdun 1860 si 1862, to fi mọ ogun Makun l’ọdun 1862 si 1864.

Latilẹ l’awọn Dahomey ti korira Ẹgba, to si jẹ pe fun bi igba mẹrin ọtọọtọ l’awọn Dahomey gbiyanju lati ṣẹgun Ẹgba, ṣugbọn ti ko ṣee ṣe fun wọn, pabo lo n ja si fun wọn.

Nigba ti gbogbo igbimọ to n ṣakoso Ẹgba dide l’ọdun 1869, iyẹn lẹyin ti gbogbo rogbodiyan ati ogun to n ja wọn ti lọ silẹ patapata, wọn pinnu lati bẹrẹ si i ni olori.

Gbogbo wọn fimọ ṣọkan lati pada lọ sile, ki wọn si lọ b’awọn eeyan wọn jiroro lati fa ẹnikan ti yoo jẹ olori wọn kalẹ, ki wọn si bẹrẹ si i jẹ ọba lọ. Gbagura wa lori ijokoo, Ake wa lori ijokoo, Oke-Ọna wa lori ijokoo, bẹẹ naa si l’awọn Owu to de gbẹyin wa lori ijokoo. Inu wọn dun, ṣugbọn awọn Oke-Ọna nikan ni wọn sọ pe awọn ko ti i ṣetan.

Lẹyin bi oṣu meloo kan, l’ọdun 1870, gbogbo wọn pada si ipade yii, wọn si l’awọn ti ṣetan lati fa ọba kalẹ laaarin ara wọn. Latigba naa ni gbogbo wọn ti bẹrẹ si i jẹ ọba. Nibẹ naa ni wọn ti pinnu orukọ ti wọn yoo maa pe ọba wọn. Awọn Ake l’awọn yoo maa pe ọba wọn ni Alake; Awọn Owu l’awọn yoo maa pe ọba wọn ni Olowu; bẹẹ naa l’awọn Gbadura l’awọn yoo maa pe ọba wọn ni Agura.

Idile meji lo wa niluu Gbagura ti wọn n jẹ ọba, awọn naa ni Ajibọṣọ ati Ẹgiri. Ọba Jamolu kinni lati idile Ẹgiri lo kọkọ jẹ l’ọdun 1870. Ọdun meje gbako lo lo lori apeere naa ko to waja l’ọdun 1877. L’ẹyin ti Ọba Jamolu waja, iporuru ọkan de ba gbogbo ilu, to fi jẹ pe ọdun meji gbako ni wọn to o pada yan ọba mi in. 1879 ni wọn ṣẹṣẹ yan Ọba Ijaade lati idile Ẹgiri kan naa, toun si lo ọdun mejidinlogun gbako.

L’ẹyin eyi l’awọn idile Ajibọṣọ naa dide wi pe awọn ni ipo naa kan, ti wọn si fa Ọba Olubunmi kalẹ l’ọdun 1897, ti kabiyesi naa si pada waja l’ọdun 1910. Ọdun naa l’awọn idile Ẹgiri fa Ọba Abọlade kalẹ lati jẹ olori wọn, ti kabiyesi si waja l’ọdun 1915. Awọn idile Ajibọṣọ wa ẹni ti wọn yoo fa kalẹ titi, wọn ko ri, lo jẹ k’awọn idile Ẹgiri tun fa Ọba Adeọṣun kalẹ l’ọdun 1915. Ọdun 1936 ni Ọba Adeọṣun kinni waja.

Ọdun 1936 kan naa yii ni idile Ajibọṣọ dide wi pe awọn yoo fa ọmọ oye kalẹ, ti wọn si fa Ọba Ṣobẹkun akọkọ kalẹ. Ọdun 1960 ni Kabiyesi ta teru nipaa. L’ọdun 1961, idile Ẹgiri fa Ọba Rauf Adeọṣun keji kalẹ, ọdun 1978 ni Kabiyesi jade laye.

Agura t’ilu Gbagura ijẹta, Ọba Halidu Laloko, Ṣobẹkun keji gb’ade l’ọdun 1980. Latigba naa ni Kabiyesi ti wa lori apeere titi di ọjọ kejila, oṣu keje, ọdun 2018 ti kabiyesi fi aye silẹ. Bi iroyin ṣe jade sita wi pe Kabiyesi ti waja l’awọn idile Ẹgiri tun ti dide wi pe awọn ti ni ọmọ oye nilẹ t’awọn yoo lo, ati pe Ọmọọba to mọ ile ati oko l’awọn fẹẹ fa kalẹ.

Gẹgẹ bi a ti mọ pe ko si ipo naa ti ko ni alatako labẹ ọrun yii, oriṣiriṣi awọn Ọmọọba lo dide wi pe awọn ni ipo naa kan, ati pe awọn mọ itan. Ṣugbọn nigba ti wọn gbe ifa janlẹ, Ifa fọn’re, o si ni Ọmọọba Saburee Babajide Bakre l’oun mu. Tani yoo tun f’ọhun niwaju, lẹyin ti Ifa ti sọrọ, ko si oluwa rẹ.

Ọjọ kejila, oṣu karun-un, ọdun 2019 ni Ọba Saburee Babajide Iṣọla Bakre, Jamolu keji lati idile Ẹgiri gb’ade. Lọjọ naa, ẹsẹ ko gbero rara, nitori pe awọn eeyan jankan-jankan kaakiri orile-ede yii ni wọn peju-pesẹ sibẹ. Aarẹ tẹlẹri l’orile-ede yii, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ wa nibẹ pẹlu. Ọjọ manigbagbe ni, nitori pe Oloye Ọbasanjọ tun fi itan tuntun balẹ, pẹlu bo ṣe dọbalẹ bi ọmọ kekere, to n ki baba agbalagba, lati ki Ọba tuntun naa.

Awọn eeyan pataki-pataki ni wọn jade lati ilu Egba Gbagura, ti won si l’okiki kaakiri agbaye. Lara wọn ni Oloogbe, Baṣọrun Mọshood Kọlawọle Ọlawale Abiọla {MKO} to jẹ gbajugbaja ẹlẹyinju aanu kaakiri agbaye; Oloogbe Efunroye Tinubu to ja fitafita fun orile-ede Naijiria wa yii ko to o jade laye; Minisita tẹlẹri fun eto ohun alumọni {mines and steel}, Alaaji Ṣarafadeen Tunji Iṣọla; gbajugba onkọwe lati ilu Wasinmi, Amos Tutuọla, at’awọn mi in bẹẹ ti a ko le darukọ tan.

Ohun kan ti mo fẹ ko ye gbogbo eeyan, paapaa awọn ọmọ ilu Gbagura ni pe orirun Gbagura bẹrẹ lati ilu Iddo si Ọṣun, Ọṣun si Ọffa, Ọffa si Awẹ, Awẹ si Ejigbo, Ejigbo si Akinmọrin, Akinmọrin si Fiditi, Fiditi si Ilọra, Ilọra si Ọyọ, Ọyọ si Ọjọọ, Ọjọọ si Ibadan, Ibadan si Ọmi Adio, at’awọn apa kan nilẹ Ibadan ko to di pe wọn de Abẹokuta ti wọn pada tẹdo si. Ibi ti wọn n pe ni Ilugun lonii ni olu-ilu Gbagura tẹlẹ, ko to di pe wọn yapa lọ sabẹ Owu, ṣugbọn ni gbara ti wọn ti yapa l’awọn eeyan ti dide wi pe Iddo ni yoo jẹ olu-ilu Gbagura.

Ninu ijijangbara ilu Ẹgba kuro lọwọ ogun Ilari ati ipọnju Ọlọyọ, awọn Gbagura ko ipa ribiribi to jọju, ti itan ko si le paarẹ. Apẹẹrẹ rẹ ni ti itẹdo kan to wa ni agbegbe Oṣiẹlẹ, eyi ti Akaaṣhi, olori ogun lati ilu Ibadan jẹ olori rẹ. Latigba naa, titi di asiko yii ni oye Akaaṣhi fi wa ninu awọn oye t’awọn Gbagura n jẹ nilu Oṣiẹlẹ.

Apa keji n bọ laipẹ.

Gbenga Ọladipupọ, gbajugbaja akọroyin lo kọ itan yii, ẹ si le pe e sori ẹrọ ibanisọrọ 07031663044

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI