Alukoro agba fun ileeṣẹ ọlọpaa lorileede Naijiria, CSP Olumuyiwa Adejọbi ti sọ pe k wọn tete lọ ọ gbe gbajugbaja oṣere ori ayelujara 'skit maker' nni, Abdullahi Maruf t'ọpọ awọn eeyan mọ si Trinity Guy lori ere lile to maa n b'awọn eeyan ṣe.
Olumuyiwa Adejọbi lo sọrọ naa lori ikanni ayelujara abẹyẹfo 'Twitter' rẹ laipẹ yii, to si ni ere ti ọkunrin naa n ṣe ti kọja oju lasan, ati pe o ni lati gba ikilọ.
Bẹ o ba gbagbe, ileeṣẹ ọlọpaa ti figba kan ri kilọ fun Trinity Guy lati din ere rẹ to n b'awọn eeyan ṣe ku, nitori pe kii ṣe gbogbo eeyan ni ara rẹ ya, ti wọn le fi ara gba awọn ere naa.
Adejọbi sọ pe lẹyin ọpọlọpọ ikilọ, Trinigy Guy kọ lati tẹle ilana ati ikilọ ti wọn fun un lori awọn ere to n gbe jade sori ayelujara, eyi to tun sọ pe o yẹ ki wọn tete fi ofin gbe e.
O wa sọ pe ki ẹnikẹni ti ara rẹ ko ba gba ere ti ọkunrin naa ba ṣe fun un, ki iru ẹni bẹẹ tete fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, nitori pe asiko ti ko rẹrin la wa yii.
“Eyi ko ni itumọ kankan rara. Mo ro pe o yẹ ki wọn ti f'ofin gbe ọmọkunrin yii.
“Awọn ti wọn ba ro pe awọn la wahala ati idaamu awọn to n ṣe ere airotẹlẹ yii f'awọn, ki wọb tete maa fi to awọn agbofinro leti, nitori pe ọpọ ere wọn lo kun fun iwa ọdaran ati ika lọ.”
No comments:
Post a Comment