Gomina ABdulRahman AbdulRazaq ti ba gbogbo awọn mọlẹbi to padanu awọn eeyan wọn sinu ijamba ori omi to waye niluu Patigi, lọjọ Aje, Mọnde to kọja, to si ni adanu nla to ya ni lẹnu ni.
Ọpọ ẹmi la gbo pe o ṣofo danu ninu ijamba ori omi naa, nibi ti ọkọ oju omi ti danu.
Ibi eto ayẹyẹ la gbọ pe awọn eeyan naa ti n bọ lọjọ naa, ko to di pe wọn pade iku ojiji ti wọn ko ro tẹlẹ, eyi to ṣeni ni kayeefi nla, to si kọja sisọ.
Gomina AbdulRazaq nigba to n sọrọ nibi abẹwo to lọ ṣe naa ṣalaye pe adanu nla ti ko ṣee gbagbe titi lai ni, to si ni ijọba yoo maa ṣe iranti awọn oloogbe naa ni gbogbo igba.
"Iṣẹlẹ ibanujẹ nla ni eyi. A ba awọn eeyan wa niluu Patigi kẹdun, paapaa Etsu tiluu Patigi, Alaaji Ibrahim Umar, Bologi keji. Iṣẹlẹ naa ba wa lọkan jẹ gidi."
Nibi abẹwo naa to ti lewaju igbimọ to lọ ṣabẹwo ibanikẹdun yii ni Gomina ti sọ pe awọn wa lati ṣe iranwọ jakẹẹti ẹgbẹrun fun aabo awọn to n rin irin ajo lori omi.
Bakan naa lo sọ pe awọn ti n ṣiṣẹ papọ pẹlu ileeṣẹ to n ri sọrọ irin ajo ori omi, iyẹn Nigeria Inland Waterway Authority (NIWA) fun titẹle ilana ati ofin ti wọn fi n rin irin ajo ori omi.
O lawọn yoo ṣagbekalẹ eto ati ilana igbalode to pe ni 'Statewide Standard Operating Procedures (SOPs), eyi ti yoo ṣakoso ẹru ti ọkọ oju omi yoo gbe, ayẹwo igbalode ko too gbera fun irin ajo, ere to gbọdọ sa, lilo aṣọ aabo ati bẹẹbẹẹlọ.
Siwaju sii lo ni ijọba oun yoo tun bẹrẹ sii ṣakoso eto irin ajo ori omi lati asiko yii lọ, lati le maa daabobo ẹmi ati dukia awọn eeyan.
No comments:
Post a Comment