Gomina AbdulRahman Abdulrazaq ti ipinlẹ Kwara ti ba ọkan lara awọn agba amofin orileede Naijiria, Amofin Mohammed Dele Belgore yọ fun ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ to n ṣe lonii, ọjọ Aiku, Sannde.
AbdulRazaq, ẹni to tun jẹ gẹgẹ bii olori awọn gomina Naijiria lo ṣapejuwe Amofin Belgore gẹgẹ bi akikanju ọmọ Naijiria to ni itara fun ilọsiwaju ati idagbasoke, paapaa lẹka eto ofin orileede yii.
O ni bi agba amofin ọhun ṣe maa n lo iwa akikanju rẹ lati fi f'awọn ọdọ ni iwuri si ibi to ga lo maa n mu ori oun wu, toun si gbọdọ maa pokiki rẹ ni gbogbo igba.
Bakan naa lo gbadura ẹmi gigun ati alaafia fun un.
No comments:
Post a Comment