Samuel fi owo ile-ẹkọ ta tẹtẹ, ko jẹ, lo ba gba ẹmi ara rẹ l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, May 28, 2023

Samuel fi owo ile-ẹkọ ta tẹtẹ, ko jẹ, lo ba gba ẹmi ara rẹ l'Ogun


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni iṣẹlẹ naa ṣi n jẹ kayeefi fun ọpọ awọn to gbọ, paapaa awọn ọrẹ gendekunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Samuel Adegoke, akẹkọọ ile ẹkọ gbogboniṣe tiluu Ilaro, iyẹn Federal Polytechnic, Ilaro lori bo ṣe deede gbẹmi ara rẹ lojiji.
 
Ohun ti a gbọ ni pe owo ile-ẹkọ ti wọn fun Samuel lo fi ta tẹtẹ ori ayelujara ti awọn oni bọọlu.
 
A gbọ pe lẹyin ti Samuel lo owo ile-ẹkọ rẹ, o tun lo owo ile-ẹkọ ọrẹ rẹ lati fi ta tẹtẹ ọhun, ṣugbọn to padanu kọja sisọ.
 
Itiju ati ibẹru bo ṣe fẹẹ ri owo naa pada la gbọ pe o mu, eyi to fa to fi gbe majele jẹ, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji. Iṣẹlẹ yii lo bi baba rẹ ninu, to fi ni wọn ko gbọdọ gbe oku rẹ wa sile foun.
 
Ipele keji ni wọn sọ pe Samuel wa l'ẹka ikẹkọọ imọ ẹrọ, Electrical Electronic Engineering.
 
Eyi to tiẹ tun wa ya ọpọ eeyan lẹnu nibẹ ni pe asiko ti awọn akẹkọọ ile-ẹkọ naa n palamọ fun idawo saa akọkọ ni Samuel gbẹmi ara rẹ, lọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii.
 
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja la gbọ pe Samuel ta tẹtẹ naa, ti ko si jẹ. Wọn sọ pe niṣe lo ji owo ile-ẹkọ ọrẹ rẹ.
 
Igba ti wọn lo rii pe ko ọna abayọ boun yoo ṣe ri awọn owo naa pada, lo mu ko pinnu lati gbẹmi ara rẹ, ni iṣẹju diẹ ki wọn bẹrẹ idanwo wọn.
 
Lara awọn ọrẹ to rin sasiko la gbọ pe wọn sare gbe e lọ si ile iwosan to wa ninu ọgba ile-ẹkọ naa, nibi ti wọn ti pada tare wọn si ọsibitu ijọba tiluu Ilaro, nibẹ si ni wọn ti kede rẹ gẹgẹ bi oku.
 
Igbakeji Olugbaniwọle sile ẹkọ naa, Ṣọla Abiala nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣalaye pe ọsibitu Hossanah lawọn sare gbe ọmọkunrin naa lọ, ati pe ko pẹ ti wọn gbe e debẹ lo dakẹ.
 
O ni baba ọmọ naa gbiyanju lati tun owo ile-ẹkọ rẹ san, ṣugbọn ti ẹpa ko pada boro mọ. Bẹẹ lo sọ pe baba naa kọ lati gba oku ọmọ rẹ, nitori pe ibanujẹ lo jẹ fun un.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI