O tan! Wọn yọ abenugọn ile igbimọ aṣofin danu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 2, 2023

O tan! Wọn yọ abenugọn ile igbimọ aṣofin danu


Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Abia ti yọ abẹnugọn wọn, Ọnarebu Chinedum Orji danu, lori ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan an, ti wọn si l'awọn yoo yan ẹlomiran ti wọn nigbagbọ ninu ẹ.
 
Oni tii ṣe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni ọmọ ile igbimọ aṣofin naa mejidinlogun bu ọwọ lu iwe wi pe awọn ko fẹ Ọnarebu Orji mọ, nitori pe iṣakoso rẹ ti su awọn.
 
Ọmọ ile igbimọ mẹrinlelogun la gbọ pe wọn wa nile igbimọ aṣofin naa, ti awọn mejidinlogun si bu ọwọ lu iwe lati yọ olori wọn danu.

Awọn ti wọn ko lọwọ si yiyọ Ọnarebu Ọrji ni, Ọnarebu Ginger Onwusibe, Solomon Akpulonu, Munachim Alozie ati Kelechi Onuzuruike.
 
Ohun ti a gbọ ni pe Ọnarebu Chukwudi Apugo (Umuahia East) lo daba yiyọ olori wọn, ti Ọnarebu Okey Igwe (PDP, Umunneochi) si ṣikeji aba naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI