Kadiri, igbakeji olori ile igbimọ aṣo fin ipinlẹ Ogun wọ gau - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, May 26, 2023

Kadiri, igbakeji olori ile igbimọ aṣo fin ipinlẹ Ogun wọ gau

 
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọwọ awọn ti igbakeji abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Ọnarebu Dare Kadiri ba ile-ẹjọ, lori ẹsun to nii ṣe pẹlu idunkoko mọ ẹmi ati iwa idaluru.

Ọjọru tii ṣe Wẹside ana ni awọn ọlọpaa wọ Ọnarebu Kadiri lọ sile ẹjọ Majisreeti to wa ni Iṣabọ niluu Abẹokuta, niwaju Onidajọ M. O. Ọṣinbajo.

Gẹgẹ bi AWIKONKO ṣe gbọ, wọn ni asiko ti Ọnarebu Kadiri n gbero lati fidi idajọ ile ẹjọ giga mulẹ, nipa bi wọn ṣe yọ ọ danu gẹgẹ bi igbakeji abẹnugọn ile igbimọ aṣofin naa lọna aitọ lọwọ ọlọpaa tẹ ẹ, iyẹn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọsẹ yii.

Bẹ o ba gbagbe, inu oṣu kẹta, ọdun 2022 ni wọn ti jawe gbele-ẹ fun Ọnarebu Kadiri, koda ti abẹnugọn ile igbimọ aṣofin naa, Ọnarebu Ọlakunle Oluọmọ kede sita pẹlu aṣẹ wi pe ko nii ba wọn jokoo papọ mọ, iyẹn ninu oṣu kẹsan, ọdun naa.

Ọnarebu Oluọmọ ninu ọrọ rẹ lọjọ naa ṣalaye pe bi wọn ṣe jawe gbele-ẹ fun Kadiri lo lọ nibamu pẹlu abala kẹrinla ati abala kẹẹdogun ninu iwe ofin to de awọn ile igbimọ aṣofin (Agbara ati anfaani), tọdun 2017.

Lati ja fun ẹtọ rẹ, Kadiri gba ile-ẹjọ lọ, nibi to ti jẹ ko di mimọ pe bi wọn ṣe jawe gbele-ẹ foun ko ba ofin mu, ati pe o jẹ aṣilo agbara fun abẹnugọn ile igbimọ aṣofin naa.

Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ O. A. Ọnafọwọkan ti ile-ẹjọ giga kẹta to wa niluu Abẹokuta paṣẹ pe ki wọn san gbogbo owo ati ẹtọ to yẹ fun Ọnarebu Kadiri to n ṣoju agbegbe Ariwa Ijẹbu keji lai fi akoko ṣofo latigba ti wọn ti da a duro.

Idajọ yii ni wọn sọ pe ko tẹ Ọnarebu Oluọmọ ati awọn eeyan rẹ nile igbimọ ọhun lọrun, ti awọn naa tun fi gba ile-ẹjọ lọ lati da Ọnarebu Kadiri lọwọ kọ, ko ma ba a wa sile igbimọ aṣofin naa lati wa fidi idajọ mulẹ.

Sibẹ, ile-ẹjọ da ẹjọ naa nu, o si paṣẹ pe ki Oluọmọ lọ san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira gẹgẹ bi owo itanran.

Lẹyin idajọ yii la gbọ pe Ọnarebu Kadiri gbe iwe idajọ, o si gba ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun lọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọsẹ yii lati lọ bẹrẹ iṣẹ rẹ pada gẹgẹ bi ọmọ ile igbimọ aṣofin, ṣugbọn ti wọn sọ pe awọn ẹṣọ aabo ko jẹ ko wọle.

Wọn ni pẹlu ibinu ni Ọnarebu Kadiri fi gbe mọto rẹ lati dina mọ gbogbo awọn to ba fẹẹ wọle sinu ọgba ile igbimọ ọhun tabi jade, wi pe ayafi ti wọn ba jẹ koun ṣe ojuṣe oun.

Nibi ti eyi ti n ṣẹlẹ la gbọ pe awọn alakoso ile igbimọ aṣofin naa ti ranṣẹ s'awọn agbofinro lati olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa ni Eleweran, ti wọn si wa gbe Ọnarebu Kadiri lọ agọ wọn.

Teṣan ọhun ni Ọnarebu Kadiri sun mọju di aarọ Ọjọru tii ṣe Wẹside, ki wọn to lọ foju rẹ ba ile-ẹjọ Majisreeti to wa ni Iṣabọ niluu Abẹokuta, nibi ti wọn ti fẹsun kan an wi pe o n dunkoko mọ ẹmi awọn eeyan, bẹẹ lo tun da wahala to le da alaafia ilu ru silẹ 

Agbefọba Lawrence Olu-Balogun nigba to n fẹsun kan Kadiri wi pe lati inu oṣu kẹta, ọdun 2022 ni wọn ti jawe gbele-ẹ fun Kadiri, ṣugbọn to ni ọkunrin naa sọ pe ile-ẹjọ ti da oun lare lati pada si ẹnu iṣẹ.

Olu-Balogun sọ pe nigba ti Kadiri de ẹnu ọna abawọle sile igbimọ aṣofin naa, lootọ l'awọn ẹṣọ aabo ko jẹ ko wọle, eyi to jẹ ko bẹrẹ awada nibẹ pẹlu wọn.

O wa sọ pe ẹsun toun ka si Kadiri lẹsẹ yii lo tako iwe ofin ọdaran tipinlẹ Ogun tọdun 2006 ni abala 86(1) ati 249(D).

Ju gbogbo rẹ lọ, Onidajọ M. O. Ọṣinbajo sọ pe Kadiri le gba beeli ara rẹ gẹgẹ bi ipo to di mu, to si sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹfa, ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI