Ileeṣẹ Pelican gba awọọdu, lo ba tu aṣiri ọna ti ileeṣẹ wọn fi dagbasoke lojoojumọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 2, 2023

Ileeṣẹ Pelican gba awọọdu, lo ba tu aṣiri ọna ti ileeṣẹ wọn fi dagbasoke lojoojumọ


Ileeṣẹ Pelican Valley Estate Limited to n ta dukia ti gba aami ẹyẹ, iyẹn awọọdu gẹgẹ bi ileeṣẹ to peregede julọ lọdun 2022, eto ọhun ti ileeṣẹ iwe iroyin Amẹbọ gbe kalẹ.
 
Laipẹ yii ni idije naa waye lori ikanni ayelujara, nibi ti awọn ileeṣẹ to n ta ilẹ ati ile, paapaa dukia ti figagbaga, ti Pẹlican si jawe olubori laaarin gbogbo wọn.
 
Eto idibo ohun to waye fun ọjọ meje gbako, ni awọn eeyan kaakiri agbaye ti dibo fun ileeṣẹ Pelican Valley Estate, nipa otitọ ati iwa ọmọluabi ti wọn fi n b'awọn eeyan dowopọ.
 
Ileeṣẹ iwe iroyin Amẹbọ News Hub to wa niluu Abẹokuta ipinlẹ Ogun, lo gbe eto idije awọọdu naa kalẹ, ẹlẹẹkeji iru ẹ si ree. Ipele-ipele si ni eto ọhun pin si, ipele ti awọn ileeṣẹ to n ta ilẹ ati ile kaakiri ipinlẹ naa.


Nigba to n gba awọọdu ọhun, Ọjọgbọn Babatunde Adeyẹmọ sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọọdu naa ko jẹ tuntun, nitori pe awọn ti gba awọọdu to le ni aadọta (50) laaarin oṣu kinni si oṣu karun-un, ọdun ti a wa yii, ṣugbọn ti eyi jẹ pataki si oun pupọ.

O sọ pe ọla inukan, iwa ọmọluabi ati otitọ t'awọn fi n ṣe lo n jẹ k'awọn maa leke ni gbogbo ọna, ti awọn si n lewaju laaarin awọn akẹgbẹ wọn kaakiri.


Agba oniṣowo naa, ẹni to tun ti figba kan ri jẹ ogbontarigi akọroyin naa gbe oṣuba kare fun alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Amebo News Hub fun ọna ti wọn n gbe awọọdu naa gba, to si jẹ ko di mimọ pe ko ni awuruju ninu, to si ṣoju-ṣaara.

Ṣaaju asiko yii ni alakoso ileeṣẹ Amebo News Hub, Ọgbẹni Ṣolankẹ Ayọmideji Taiwo sọ pe inu oun dun wi pe awọn eeyan mọ riri ipa ti ileeṣẹ Pelican Valley Estate n ko lẹka ọrọ ile gbigbe ati dukia, to si ni ọkan pataki lara awọn to n jẹ ki ipinlẹ Ogun ati agbegbe ẹ dagbasoke ni.


Bẹẹ lo gba Ọjọgbọn Adeyẹmọ lamọran lati tẹsiwaju ninu ọna ti wọn n gba lati ṣakoso ileeṣẹ wọn, eyi to n jẹ ki wọn maa lewaju ni gbogbo igba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI