Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa lọjọ Aiku tii ṣe Sannde ana ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ baale ile, ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin kan, Aminu Abubakar lori bo ṣe lu iyawo rẹ, Nana Fadimatu pa.
B'awọn kan ṣe n sọ pe asasi ni, bẹẹ l'awọn kan n sọ pe eedi ni, eyi to mu ki awọn miran maa pariwo pe idajọ ododo gbọdọ waye lori iṣẹlẹ ọhun.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni awọn kan lo ta Abubakar lolobo wi pe iyawo rẹ to lu pa yii, Nana, ẹni ọdun mejidinlogoji n gbero lati lọ fẹ ọkunrin miran.
Wọn ni awọn to ṣeke naa fun Abubakar lọjọ Ẹti tii ṣe Furaidee, ọsẹ to kọja yii sọ pe ọjọ Abamẹta to jẹ Satide ni iyawo rẹ naa fẹẹ ko lọ sile ọkọ tuntun to ṣẹṣẹ pade.
Nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Furaide naa ni wọn sọ pe Abubakar ki Nana mọlẹ, to si bẹrẹ sii luu bi ẹni n lu ilu ọdun egungun.
Ariwo ati igbe obinrin naa lo ta si awọn ara agbegbe Lelewaju to wa ni Ṣhagari Phase 2, ijọba ibilẹ Guusu Yola, ipinlẹ Adamawa leti, to fi di pe wọn sare dide lati gba Nana silẹ.
O ṣeni laanu wi pe ki wọn too debẹ, eleeru ti sunko, obinrin naa ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa, Suleiman Nguroje gbe sita, sọ pe ilukulu ni Abubakar lu iyawo ẹ lọjọ to jẹ ọjọ karun-un, oṣu karun-un, ọdun ti a wa yii.
Bẹẹ lo sọ pe iwadii ti n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ ọhun, ati pe Abubakar yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.
No comments:
Post a Comment