Ajọ NDLEA rọwọ to gendekunrin mẹtadinlogun pẹlu egboogi oloro ati ibọn l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, May 26, 2023

Ajọ NDLEA rọwọ to gendekunrin mẹtadinlogun pẹlu egboogi oloro ati ibọn l'Abẹokuta


Ko din ni gendekunrin mẹtadinlogun ti ọwọ ajọ to n gbogun ti asilo oogun ati agbebogi oloro lorileede Naijiria, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA) lori ẹsun wi pe wọn n mu igbo, ati pe wọn tun ba ibọn lọwọ wọn.
 
Agbegbe bii Ọbada, Lafẹnwa, Odo-Ẹran ati Adigbẹ lọwọ palaba awọn eeyan naa ti segi nigboro ilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Egboogi oloro ti iwọn rẹ ko din ni 6.2kg la gbọ pe wọn gba lọwọ wọn lakoko ti ọwọ ba wọn.
 
Gẹgẹ bi ọga agba ajọ naa nipinlẹ Ogun, Ibiba Odili ṣe ṣalaye ninu atẹjade to fi sita l'Ọjọbọ tii ṣẹ Tọsidee, ọsẹ yii, lo ti jẹ ko di mimọ pe nipa ajọṣepọ awọn oṣiṣẹ ologun ati ẹṣọ aabo ara ẹni laabo ilu ti a mọ si Sifu Difẹnsi lọwọ fi tẹ gbogbo wọn.

Odili sọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lati rii pe ọwọ tẹ awọn yooku, ati pe wọn yoo foju ba ile ẹjọ lẹyin iwadii.
 




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI