Ọwọ ileeṣẹ eto aabo Amọtẹkun n'ipinlẹ Ogun ti tẹ baale ile, ẹni ogoji ọdun kan, Ṣodade Ṣẹsan lori ẹsun gbigbero lati paniyan, ati lati ji dukia ẹni to fẹẹ pa salọ.
Gẹgẹ bi David Akinrẹmi to jẹ ọga agba Amọtẹkun n'ipinlẹ Ogun ṣe ṣalaye, o sọ pe ọjọ kẹrin, oṣu kẹrin, ọdun ti a wa yii lọwọ tẹ Ṣẹsan niluu Iṣara-Rẹmọ, lakoko to n gbero lati ta ọkada to digun gba.
Akinrẹmi sọ pe ọlọkada naa, Mohammed Bashiru lo jade lọjọ naa, pẹlu erongba lati fi ọkada rẹ wa ounjẹ sẹnu ara rẹ. Nibi ti wọn lo ti n lọ ni Ṣẹsan ti daa duro pe ko gbe oun lọ siluu Ipẹru-Rẹmọ, ati pe yoo tun gbe oun pada, nibẹ ni wọn ti jọ ṣadehun si ẹgbẹrin naira.
Wọn ni bi wọn ṣe de Ipẹru, ti Ṣẹsan rii pe ero pọ lagbegbe naa, lo mu ko sọ pe ko tun sare gbe oun de ile ọti kan ti wọn pe ni Abuja Bar, eyi to wa niluu Iliṣan, iyẹn ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ.
Bi wọn ṣe de agbegbe naa la gbọ pe agbegbe ọhun pa lọlọ, awọn eeyan ko si kọja. Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe Ṣẹsan ti yọ ọbẹ to fi n ṣiṣẹ buruku lapo jade, to si fi rẹ ọlọkada naa lọrun, ko to tii danu, to si gbe ọkada naa salọ.
Awọn to kọja lasiko ti ọlọkada yii n pokaka iku lẹgbẹ opopona to wa ni wọn ṣe iranwọ lati gbe e lọ si ọsibitu, lati doola ẹmi ẹ. Lẹyin to si gba itọju tan ni wọn lo gba ọdọ awọn Amọtẹkun lọ lati fi to wọn leti.
Iwadii fi han pe ilu Iṣara Rẹmọ ni Ṣẹsan gbe ọkada naa salọ, koda ti wọn sọ pe ibi to gbe e si lati wa onibara fun un ni wọn ti ka a mọ, ti wọn si gbe oun ati ọkada naa lọ teṣan wọn.
Akinrẹmi ṣalaye pe nigba ti awọn n fi ọrọ wa ọlọkada naa lẹnu wo, o sọ pe itosi ṣọọṣi Anglican to wa ni Ode-Rẹmọ ni Ṣẹsan ti pe oun lati gbe oun, lai mọ pe o ni iṣẹ buruku to fẹẹ ṣe lọkan.
Ọga agba naa sọ pe ni kete ti Ṣẹsan ti gba ọkada ọhun, lo ti gbe e lọ sile, to si yọ nọmba idanimọ ara ọkada naa to jẹ SGM 220 WA, eyi ti wọn lọwọ rẹ to ẹgbẹrun lọna irinwo aabọ [N450,000] naira danu, to si ju si ṣalanga.
O ni ile iwosan Ogere Medical Centre ni wọn gbe ọlọkada naa lọ fun itọju, ko to di pe ọwọ palaba Ṣẹsan segi.
Bẹẹ lo sọ pe Ṣẹsan ti jẹwọ pe lotitọ loun digun jale naa, ṣugbọn toun ko mọ pe aṣiri maa pada tu, to si ti n bẹbẹ fun oju aanu.
Akinrẹmi sọ pe ile-ẹjọ nikan lo le gbọ ẹbẹ Ṣẹsan, nitori pe awọn yoo foju rẹ ba ile ẹjọ lẹyin iwadii awọn.
No comments:
Post a Comment