Ori oku ti ko din ni aadọta ni mo ti ji wu - Solomon tọwọ tẹ n'Ipokia jẹwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 8, 2023

Ori oku ti ko din ni aadọta ni mo ti ji wu - Solomon tọwọ tẹ n'Ipokia jẹwọ


Boroboro ni gendekunrin kan ti won pe oruko re ni Gbesemehan Dewanu Solomon n ka nigba towo palaba re segi, nibi to ti lo ji ori oku wu ninu saare lagbegbe kan ti wọn pe ni Idologun niluu Ipokia, ijoba ibile Ipokia, ipinle Ogun.
 
A gbo pe Solomon ko niṣẹ meji to kọja ko wu ori awọn oku lọ, ko si ta a f'awọn to n ṣetutu owo tabi aajo ọla kaakiri Ipokia ati agbegbe ẹ lọ.
 
Lati bi oṣe meloo kan sẹyin ni wọn lawọn araalu Ipokia ti n pariwo wi pe awọn kan n ji ori oku wu, ti wọn si ti fi to awọn ọlọpaa ati awọn oṣiṣẹ eleto aabo miran kaakiri ipinlẹ Ogun leti.
 
Wọn ni bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa atawọn eleto aabo naa n ṣiṣẹ iwadii wọn lọ, ṣugbọn sibẹ, awọn araalu ko da iṣẹ naa da awọn eleto aabo nikan, to si mu k'awọn naa bẹrẹ iṣẹ iwadii.
 
Oru ọganjọ nigba ti gbogbo eeyan ti lọ sun la gbọ pe Solomon tun de pẹlu iwa rẹ, to si tun fẹ lọ wu ori oku, gẹgẹ bi iṣe rẹ.
 
Nibi ti wọn lo ti jokoo sidii saare kan lati tun ji ori oku wu, lọwọ palaba rẹ ti segi. Wọn lawọn araalu gangan ni wọn rọwọ to o, to si n bẹbẹ fun oju aanu.
 
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii lọwọ tẹ Solomon, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Ọba Yisa Ọlaniyan to jẹ Onipokia tiluu Ipokia nigba to n sọrọ kọminu pupọ lori iwa ti Solomon n hu, to si lo ku diẹ kaato.
 
Kabiyesi naa lo parọwa wi pe ki wọn lọ fa Solomon le awọn ọlọpaa lọwọ, pẹlu ẹbẹ wi pe ki wọn ṣe iwadii rẹ finnifinni, lati mu awọn yooku ẹ ti wọn jọ n ṣiṣẹ buruku naa, paapaa awọn to n ta ori awọn oku naa fun.
 
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi ko tii sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ naa, ṣugbọn ti a pada gbọ pe iwadii ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI