Ọrẹ mẹta to n ṣoogun f'awọn 'Ọmọ Yahoo' ti ha o, poosi mẹta ọtọọtọ ni wọn ba lọwọ wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, April 7, 2023

Ọrẹ mẹta to n ṣoogun f'awọn 'Ọmọ Yahoo' ti ha o, poosi mẹta ọtọọtọ ni wọn ba lọwọ wọn


Ileeṣẹ ọlọpaa ilu Abuja ti foju awọn mẹta kan han wi pe wọn ko niṣẹ meji ju iṣẹ babalawo lọ, ti wọn si lawọn lo n ṣoogun f'awọn ọmọ Yahoo ti wọn n lu jibiti ori ayelujara.
 
Uluko Adukwu, ẹni ọdun mejidinlọgbọn; Salisu Aduh, ẹni ọdun mejidinlogoji ati Adams Halilu, toun jẹ ọmọ ọdun mẹrinlelogun l'awọn mẹta tọwọ tẹ.
 
Agbẹnusọ ọlọpaa ẹkun Zone 7 l'Abuja, SP Istifanus Sunday Bako, nigba to n sọrọ l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, to kọja yii sọ pe awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ wọn lo yawọ Jikwoyi ati Orozo to wa loju ọna Karu l'Ọjọru, Wẹsidee.

Bako sọ pe ọmọ bibi ipinlẹ Kogi l'awọn mẹtẹẹta, ṣugbọn ilu Abuja ni wọn n gbe.
 
Yatọ si awọn mẹta tọwọ tẹ yii, ọwọ tun tẹ ọmọdekunrin meji ti ọjọ orui wọn ko ju ọdun mọkanla si mẹtala lọ.
 
O lawọn mẹtẹẹta jẹwọ pe jibiti l'awọn n lu, ati pe awọn tun ṣoogun f'awọn ọmọ Yahoo lati maa fi lu awọn onibara wọn ni jibiti.
 
Poosi mẹta, mọto Toyota Prado kan, Lexus 330 kan, ati foonu olowo nla mẹẹdogun ni wọn gba lọwọ wọn
 
Yatọ si eyi, wọn tun ba awọtẹlẹ awọn obinrin, iyẹn awọn ti wọn ti pa danu lọwọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI