Ẹgbẹ awọn akọroyin Yoruba kaakiri orileede Naijiria, Guild of Yoruba Media Practitioners, GYMP ti lalẹhu, lati mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba kikọ ati kika ẹdẹ Yoruba lagbaye.
Gẹgẹ bi a gbọ, ilu Eko ni olu ileeṣẹ ẹgbẹ naa wa.
Awọn agbaagba ninu iṣẹ iroyin lede Yoruba ni wọn wa ninu ẹgbẹ ọhun, koda ti awọn alakoso ileeṣẹ AWIKONKO MEDIA CHANNEL to n gbe Iroyin Awikonko jade ni gbogbo igba naa wa ninu ẹgbẹ ọhun.
Ninu atẹjade ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Johnson Akinpẹlu gbe jade lorukọ alaga ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Samuel Akinrole, o ni lojuna lati ma jẹ ki ede, aṣa ati iṣe Yoruba parun, lo mu ki ẹgbẹ naa jade.
Akinpẹlu sọ pe anfaani ati aaye ṣi silẹ f'awọn to ba fẹẹ darapọ mọ ẹgbẹ ọhun, ati pe kii ṣe gbogbo eeyan lo le darapọ, bi ko ṣe awọn akọroyin Yoruba.
No comments:
Post a Comment