Titi di asiko ti a pari akojọpọ yii la gbọ pe awọn agbofinro ṣi fi n wa ọkunrin awakọ kan tẹnikẹni ko tii mọ orukọ rẹ, lori bo ṣe fi mọto rẹ gba ọlọkada ati awọn meji kan, to si na papa bora.
Agbegbe ti wọn n pe ni Okemọsan to wa lopopona Abẹokuta si Ṣagamu, Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni ijamba naa ti waye ni nnkan bi aago marun-un aarọ, ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii.
Gẹgẹ bi Florence Okpe to jẹ agbẹnusọ fun ajọ ẹṣọ oju popona tijọba apapọ, Federal Road Safety Corps (FRSC) nipinlẹ naa ṣe ṣalaye, o ni awọn kan lo ta ileeṣẹ wọn lolobo, ti wọn fi sare debẹ lati doola ẹmi awọn ti onimọto naa gba.
O sọ pe eeyan mẹta ni awakọ naa gba, ọlọkada kan ati awọn meji to gbe sẹyin, to si ni awọn oṣiṣẹ wọn ba awọn eeyan ọhun nilẹ, nibi ti wọn ti n japoro iku.
Loju ẹsẹ lo sọ pe wọn ti gbe wọn lọ si ọsibitu ijọba apapọ, Federal Medical Centre, FMC to wa ni Idi-Aba niluu Abẹokuta lati doola ẹmi wọn.
Okpe ni o ṣeni laani pe awọn meji ku lọsibitu naa, to si lawọn ti ranṣẹ s'awọn mọlẹbi wọn, lati fa oku le wọn lọwọ
Ahmẹd Umar to jẹ ọga agba ajọ naa nipinlẹ Ogun nigba to n banujẹ lori iṣẹlẹ ọhun sọ pe ka ni awakọ naa ti gbiyanju lati gbe awọn eeyan naa lọ si ọsibitu, o lo ṣeeṣe ki wọn ku.
Bẹẹ lo gbawọn awakọ lamọra lati rọra maa sare, ki wọn si maa foju sọna wo awọn to n kọja lọ, lati dẹkun ijamba.
No comments:
Post a Comment