Ko di ni gendekunrin mẹfa tọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹka tiluu Abuja tẹ laipẹ yii lori ẹsun jibiti ori ayelujara ti a mọ si 'Yahoo-Yahoo', eyi ti wọn fi kan wọn.
Ọjọ Iṣẹgun tii ṣe Tusidee la gbọ pe ọwọ tẹ awọn mẹfa naa lagbegbe Jahi ati Dawaki to wa niluu Abuja, lẹyin olobo ti wọn lo ta wọn.
Ninu atẹjade ti ajọ naa gbe jade l'Ọjọru, Wẹsidee, ni wọn ti darukọ awọn mẹfẹẹfa naa; Emmanuel Ndubuisi, Solomon Tochukwu, Okotie Kingsley, Benedict Akor, Samuel Anosike ati Samson Iffy.
Mọto Mercedes Benz kan; Lexus RX350 ati Toyota Camry ni wọn gba lọwọ wọn.
Awọn nnkan miran ti wọn tun gba lọwọ wọn ni; ẹrọ kọmputa alagbeka loriṣiriṣi, foonu olwo nla loriṣiriṣi, iwe irinna ati awọn aago ọwọ olowo nla.
Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe wọn yoo foju wọn ba ile ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.
No comments:
Post a Comment