O pari! Gbajumọ pasitọ gbe foonu mejilelaadọta ati owo ọrẹ awọn ọmọ ijọ salọ, lẹyin isọji ita gbangba n'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, April 7, 2023

O pari! Gbajumọ pasitọ gbe foonu mejilelaadọta ati owo ọrẹ awọn ọmọ ijọ salọ, lẹyin isọji ita gbangba n'Ibadan


Ọrọ buruku toun tẹrin, nigba ti wọn sọ pe gbajugbaja pasitọ kan niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ gbe foonu ti ko din ni mejilelaadọta to jẹ t'awọn ọmọ ijọ, ati owo wọn salọ.

Pasitọ naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Dokita Owen Abraham la gbọ pe o wa lati orileede Gambia, o si wa siluu Ibadan, nibi to ti gbe isọji ita gbangba ọlọjọ mẹta kalẹ.

AWIKONKO gbọ pe nigba ti Pasitọ Owen de, obinrin kan lo lọ ba lagbegbe Apọnrin, Agbowo niluu Ibadan, to si ba a sọrọ pe Ọlọrun lo ran oun lati wa ṣe isọji, ati pe oun fẹẹ ṣe iranlọwọ f'awọn ọdọ ati awọn opo.

Wọn ni ṣe ni Owen sọ pe k'awọn eeyan gba aawẹ lasiko isọji ita gbangba naa, ki adura wọn le tete gba, lai mọ pe ẹtanjẹ lasan ni.
 
Lọjọ ti isọji naa pe ọjọ kẹta ni wọn sọ pe Owen ni k'awọn eeyan da foonu wọn jọ, nitori pe oun ko fẹ ki ohunkohun di wọn lọwọ lati gbọ ohun Ọlọrun.
 
Lojiji ni wọn sọ pe Owen poora mọ awọn ọmọ ijọ loju, pẹlu foonu mejilelaadọta, owo ati awọn dukia miran, lai jẹ kẹnikẹni mọ ibi to lọ.
 
Ọkan lara awọn to kagbako Owen, Arabinrin Grace Akintọla, nigba to n sọrọ sọ pe niṣe lo wa fi ẹbun tan wọn jẹ.
 
Ninu ọrọ Arabinrin Grace, to tun jẹ opo, o ni "Ọmọbinrin Ibo kan ni pasitọ naa lọ ba ladugbo wa lati ba a wa awọn eeyan, paapaa awọn opo ati akẹkọọ, wi pe oun fẹẹ ran wọn lọwọ.

“Ẹnikan ladugbo wa lo pe mi sibi ipade naa. Aṣọ awọn pasitọ lọkunrin naa wọ. O loun maa ra ile ọkan ninu wa, oun yoo si ra ẹṣọ sinu ile naa.

“O tun ṣeleri f'awọn to ba kopa ninu ipade ọhun lati fun wọn lowo, koda, o lawọn oloṣelu ko le fun awọn eeyan ni iru owo bẹẹ.

“Lọjọ ti isọji naa maa pari, o ta ike omi kan ni ẹgbẹrun marun-un naira din n'igba {N4,800}. O ni ododo oloorun didun wa ninu omi t'awọn eeyan san owo ẹ naa.”

Ẹlomiran toun jẹ akẹkọọ fasiti Ibadan, ẹni to ni ka forukọ boun laṣiri sọ pe pasitọ naa paṣẹ f'awọn lati gbaawẹ fun ọjọ mẹta.
 
“O ni ka ko foonu wa wa, lati le gbajumọ adura ti a wa gba, lai mọ pe o fẹẹ ko awọn ẹru wa salọ ni.
 
“O loun ko fẹ ki foonu kankan dun, idi ree to fi gba awọn foonu naa. Koda, obinrin kan dide lati ya fọto rẹ, ṣugbọn niṣe lo gba foonu obinrin naa.
 
“Lọjọ ti isọji naa maa pari, o loun fẹ lọ sinmi ni otẹẹli kan toun de si, nigba to ya lo sọ pe oun fẹ lọ jẹun ni fasiti Ibadan, a ko mọ bo ṣe salọ pẹlu awọn ẹru wa.
 
“Gẹgẹ bi ojiṣẹ Ọlọrun, a bọwọ fun un gidi, a ko mọ pe niṣe lo fẹẹ fi orukọ Ọlọrun lu wa ni jibiti.”
 
Ni bayii, a gbọ pe awọn eeyan ti kede rẹ gẹgẹ bi ẹni ti wọn n wa, pẹlu bi wọn ṣe fi fọto isọji rẹ sita lati sọ pe awọn n wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI