O ma ṣe o! Wọn ba oku baba rugbo leti odo n'Ijẹbu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, April 21, 2023

O ma ṣe o! Wọn ba oku baba rugbo leti odo n'Ijẹbu


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni oku baba arugbo kan ti a ko tii mọ orukọ rẹ ṣi n jẹ kayeefi f'awọn to rii, paapaa awọn ara agbegbe opopona Owu Ijẹbu si Ijẹbu Imuṣhin, iyẹn nijọba ibilẹ Ijẹbu East, ipinlẹ Ogun.
 
Bawọn kan ṣe n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn amookun ṣeka lo fi baba arugbo naa ṣẹṣo, bẹẹ lawọn kan n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe ebi lo pa baba naa ku.
 
Ohun t'awọn miran tun n sọ ni pe o le jẹ pe aisan kan to ti n ṣe baba naa lọjọ pipẹ lo pada ṣeku pa a seti odo ọhun, ṣugbọn ju gbogbo rẹ, ko tii sẹni to le fidi iku to pa baba arugbo naa mulẹ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.

AWIKONKO gbọ pe ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni wọn ṣalabapade oku baba naa leti odo Ogbe to wa lopopona Owu Ijébu si Ijẹbu Imuṣhin.

Gẹgẹ bi awọn to fi iroyin ọhun to wa leti ṣe ṣalaye, wọn ni awọn oṣiṣẹ tọrọ naa kan nijọba ibilẹ ni wọn lọ gbe oku baba naa lọ si mọṣuari.
 
Bẹẹ lawọn to gbe iroyin naa sita sọ pe ki wọn pe nọmba 07055358535 ti wọn ba ni ohunkohun lati sọ lori oku baba naa, tabi pe wọn mọ awọn to nii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI