O ma ṣe o! Lẹyin ogun ọdun-le to ti n wa ọmọ, gbajumọ oniṣowo ku toyun-toyun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, April 16, 2023

O ma ṣe o! Lẹyin ogun ọdun-le to ti n wa ọmọ, gbajumọ oniṣowo ku toyun-toyun


Niṣe  ni ariwo ibanujẹ sọ kaakiri ori ikanni ayelujara nigba ti iroyin iyaale ile, ẹni ọdun mọkandinlaadọta kan, Arabinrin Adenikẹ Adewunmi-Adebisi, ẹni ti wọn lo ku toyun-toyun jade sita.
 
Odu ni Adenikẹ, kii ṣaimọ foloko lagboole iṣowo ori ayelujara, to tun jẹ oniroyin ori ayelujara ti a mọ si 'Blogger', to si tun jẹ ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹyin Bọla Ahmẹd Tinubu.
 
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn ni Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee to kọja yii ni obinrin naa dagbere faye l'ọsibitu ti wọn sare gbe e lọ lati doola ẹmi rẹ.
 
Aburo Adenikẹ, iyẹn Jọkẹ Adewunmi-Tọba to kede sita lori ayelujara ti Fesibuuku lo ṣalaye pe ẹgbọn oun ti n wa ọmọ latigba to ti ṣegbeyawo l'ogun ọdun sẹyin, to si jẹ ko di mimọ pe oyun to ni lo pada ṣeku pa a.
 
Ologbe to jẹ oludasilẹ Nikkisworldblog la gbọ pe adura rẹ gba, to si ti loyun. Oyun naa lo n reti lati fi bi ọmọ ko to di pe nnkan yiwọ fun un lọjọ naa, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.
 
Jọkẹ sọ pe niṣe ni ẹgbọn oun sọ pe oun ko le min delẹ daadaa, eyi to jẹ ki wọn sare gbe e lọ si ọsibitu fun itọju, to si lo jẹ iyalẹnu nigba to dakẹ loju ọna, ki wọn too de ọsibitu naa.
 
“Iwe Roomu 14:8 – Bi a ba wa laaaye, a wa laaaye fun Oluwa; bi a ba si ku, a ku fun Oluwa. Nitori naa, bi a wa laaaye, tabi bi a ku, ti Oluwa ni awa i se. Fun ogun ọdun le sẹyin, ẹgbọn mi, Adenikẹ Adewunmi Adebisi duro lati woju Ọlọrun fun ọmọ. Ọlọrun ṣe e, ṣugbọn o ṣeni laanu pe oyun naa ṣeku pa oun ati ọmọ inu ẹ laarọ yii (13/04/2023).

“O sọ pe oun ko le min delẹ, o si ku ko to di pe wọn gbe e de ọsibitu. O tiẹ ti n mura silẹ fun ayẹyẹ ọjọ ibi aadọta ọdun rẹ, ko si wa ṣe isọmọlorukọ lẹyin rẹ lọdun yii. Ẹ dakun, ẹ gbadura fun wa, nitori pe irora yii pọ kọja sisọ. O daarọ o ẹgbọn mi atata”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI