Nitori gbese ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira, adajọ ni ki wọn lọ yẹgi fun Festus - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, April 21, 2023

Nitori gbese ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira, adajọ ni ki wọn lọ yẹgi fun Festus


Adajọ ile ẹjọ giga t'ipinlẹ Adamawa ti paṣẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun Festus Stephen titi ẹmi yoo fi bọ lara rẹ, lori ẹsun wi pe o ṣeku pa ọrẹ rẹ, Mohammed Sani, nitori tiyẹn ko fẹẹ san gbese ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira to jẹ ẹ.
 
Onidajọ Bulila Ikharo sọ pe iwadii ati ẹri fidi rẹ mulẹ daju pe Festus lo pa Sani, ẹni tọpọ awọn eeyan tun mọ si Jẹga nitori gbese ẹgbẹrun lọna ọgbọn to jẹ ẹ.

Gẹgẹ bi ẹsun ti wọn fi kan Festus to wa lati agbegbe Sabon Pegi bye-pass niluu Yola, ijọba ibilẹ Yola South, wọn ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2018 ni Fẹstus pa Jẹga lagbegbe Sabon Pegi.
 
Wọn ni ṣe lo fọ igi mọ ọn titi tiyẹn fi gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra lọjọ naa.

A gbọ pe Fẹstus ya Jẹga lowo, ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira, to si ṣeleri lati da owo naa pada ni kete to ba ti rii. Wọn nigba ti ọjọ ti Jéga ṣeleri lati da owo naa pada pe, o kọ lati san owo ọhun pada fun Festus.
 
Gbogbo bi Festus ṣe beere owo naa lọwọ Jẹga, ni ko daa lohun. Lọjọ naa ni wọn sọ pe Festus fibinu lọ sọdọ Jẹga lati gba owo naa tipatipa, ṣugbọn tiyẹn loun ko tii ni.
 
Eyi ni wọn lo jẹ ki Festus binu, to si yọwọ ẹṣẹ si Jẹga. Jẹga naa nigba ti wọn ko gbe ọwọ tiẹ naa fun alagbafọ, lo ba doju ija kọ Festus, bayii ni wọn ṣe bẹrẹ sii jija igboro.
 
Awọn kan tiẹ sọ pe egboogi oloro Codeine ati Indian Hemp, lawọn mejeeji gbe lura, ko to di pe wọn bẹrẹ sii wa nnkan ija oloro ti wọn fi oju ara wọn.
 
Wọn nibi ti Jẹga ti fẹẹ yọ ọbẹ to fi sabẹ bẹẹdi rẹ, ni Festus ti sare fa ada yọ, to si ṣa Jẹga si wẹwẹ. Ori ni wọn lo ti ṣa a, ti ẹjẹ si bo o. Loju ẹsẹ nibẹ lo ti dakẹ.

Nigba ti wọn ni Festus rii pe Jẹga ti ku, niṣe lo mu Siga, to si tilẹkun mọ ọn sinu ile, ko to salọ si Mubi, iyẹn lagbegbe Ariwa Adamawa lati farapamọ. Nibẹ ni wọn lo tun ti daran miran.
 
Yatọ si pe wọn da ẹjọ iku fun Festus, wọn lo tun ṣi ni ẹjọ miran lati jẹ lori ẹsun miran niwaju adajọ miran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI