Iṣakoso to n bọ gbọdọ f'opin si ẹlẹyamẹya ti idibo 2023 da silẹ ni Naijiria - Ọbasanjọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, April 7, 2023

Iṣakoso to n bọ gbọdọ f'opin si ẹlẹyamẹya ti idibo 2023 da silẹ ni Naijiria - Ọbasanjọ


Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti gba ijọba to n bọ lamọran lati f'opin si ọrọ iyapa ati ẹlẹyamẹya to n ṣẹlẹ lakoko yii, eyi ti eto idibo da silẹ.
 
Ọbasanjọ sọ pe bi iṣakoso to n bọ ba le gbiyanju lati dẹkun wahala ati iwa ibanujẹ ti idibo to kọja da silẹ laaarin awọn ọdọ, yoo dara pupọ.
 
Aarẹ tẹlẹri naa lo sọrọ yii lakoko to n sọrọ nibi ipade ti ẹgbẹ Nextier and the Ibadan School of Governance and Public Policy gbe kalẹ niluu Abuja, eyi ti wọn pe akori ẹ ni “From Elections to Governance and Performance”.
 
O ni iṣakoso lorileede Naijiria ti gba ki eeyan ronu kọja ibi ti awọn eeyan ba foju si, lati le gba orileede silẹ, paapaa lati mu ilu kuro ninu oko gbese.
 
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ wi pe o yẹ keeyan lo itara oṣelu ati igbese, pẹlu idari to ye kooro lati mu idagbasoke ba ilu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI