Ikunlẹ abiyamọ o! Ijamba mọto f'ẹmi eeyan mejila ṣofo l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, April 16, 2023

Ikunlẹ abiyamọ o! Ijamba mọto f'ẹmi eeyan mejila ṣofo l'Ogun


Ko din ni eeyan mejila ti wọn padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọkọ n'ipinlẹ Ogun laaarin Ọjọru, Wẹsidee ati Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ ti a wa yii.
 
Iroyin iku awọn marun-un lo kọkọ waye lopopona marosẹ Ẹpẹ si Ijẹbu-Ode l'Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, nigba ti wọn sọ pe tirela nla kan lo lọ ya ba awọn marun-un naa, ti wọn wa ninu mọto Benz, to si tẹ wọn pa.
 
A gbọ pe mọto Benz naa ti nọmba idanimọ rẹ jẹ BWR 281 XC, lo jẹ ti ileeṣẹ kan ti wọn jẹ agbaṣẹṣe. Ninu ijamba naa ni wọn tun sọ pe ọlọkada kan naa wa, to si pa gbogbo wọn danu.
 
Babatunde Akinbiyi to jẹ agbẹnusọ, ajọ ẹsọ oju popona nipinlẹ Ogun, Traffic Compliance and Enforcement (TRACE) nigba to n fidi rẹ mulẹ sọ pe ere asapajude ti ẹni to wa tirela naa wa lo mu ko lọ ṣakoba f'awọn to n lọ jẹjẹ wọn.
 
O ni ilu Ẹpẹ ni tirela Mack naa ti n bọ, to fi dẹmi awọn eeyan naa legbodo, to si lawọn ti ko awọn oku naa lọ ọsibitu ijọba to wa ni Ijẹbu-Ode.
 
Lẹyin rẹ ni ijamba miran tun waye l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, iyẹn ni nnkan bi aago mẹsan kọja iṣẹju mọkanlelogun, lagbegbe afara Ṣaapade to wa loju ọna Ekoo si Ibadan.
 
Florence Okpe to jẹ agbẹnusọ fun ajọ ẹṣọ oju popona t'ijọba apapọ, Federal Road Safety Corps, FRSC, ṣalaye pe eeyan mẹtadinlọgbọn ni wọn fara kaaṣa ninu ijamba naa.
 
Okpe sọ pe ọkunrin marundinlọgbọn ati obinrin meji ni wọn, to si ni ọkunrin mẹtadinlogun ati obinrin kan ni wọn farapa yannayanna, ti awọn meje yooku si dagbere faye loju ẹsẹ.
 
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o ni ṣe lawọn meje naa jona kọja idanimọ ninu ijamba mọto Toyota Sienna, ti nọmba idnaimọ rẹ jẹ BWR762PV, ati mọto bọọsi akero Mazda ti nọmba idanimọ rẹ jẹ BDN18 LG.
 
O sọ pe niṣe ni wọn fori gba ara wọn, lori ere asapajude ti wọn jọ wa, ti wọn si lana loju ẹsẹ.
 
Bẹẹ lo jẹ ko ye wa pe ọsibitu Victory to wa niluu Ogere, ati ọsibitu Idẹra to wa niluu Ṣagamu ni wọn ko awọn to farapa lọ, lati gba itọju, to si ni mọṣuari FOS to wa niluu Iṣara ni wọn ko awọn to jona ku naa lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI