Iroyin yajoyajo to tẹ AWIKONKO lọwọ ti jẹ ko di mimọ pe adajọ agba tẹlẹ lorileede Naijiria, Onidajọ-fẹyinti Ọmọọba Bọlasọdun Adesunmbọ Ajibọla ti ọpọ awọn eeyan mọ si Bọla Ajibọla ti jade laye.
Bọla Ajibọla, ẹni to tun ti figba kan ri jẹ Onidajọ ile ẹjọ agba, iyẹn International Court of Justice ti Hague to wa lorileede Netherlands lo jade laye lẹni ọdun mọkandinlaadọrun-un (89).
Oloogbe naa to tun jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ fasiti Crescent to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni wọn lo ku lẹyin aisan ọjọ pipẹ to nii ṣe pẹlu ọjọ ogbo.
Aarọ oni, ọjọ Aiku tii ṣe Sannde ni akọbi oloogbe naa, Ṣẹgun Ajibọla toun naa kẹ agba amofin (SAN) kede iku baba rẹ, to si jẹ ko di mimọ pe oru mọjumọ ni baba naa fi aye silẹ.
No comments:
Post a Comment