Gbọngan imọ ijinlẹ 'Innovation Hub' t'ijọba Kwara n kọ s'Ilọrin ti fẹẹ pari - Ijọba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 8, 2023

Gbọngan imọ ijinlẹ 'Innovation Hub' t'ijọba Kwara n kọ s'Ilọrin ti fẹẹ pari - Ijọba


Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe gbọngan imọ ijinlẹ ti awọn oloyinbo n pe ni Innovation Hub, eyi ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq n kọ lọwọ siluu Ilọrin ti de ipele to kẹyin lati pari.
 
Ni nnkan bi oṣu meloo kan sẹyin ni ijọba Kwara pari Gbagede aṣa ti wọn pe ni Visual Arts Centre, siluu Ilọrin bakan naa, ṣugbọn Innovation Hub yii tun ṣara ọtọ fun idagbasoke ati ilọsiwaju ipinlẹ naa nipa imọ igbalode ti tẹkinọlọji.
 
Ijọba sọ pe ipele ti kikọ gbọngan naa wa bayii ti n fẹẹ de ipele to kẹyin lati pari, nitori pe iṣẹ ti lọ kọja ohun ti ẹnikẹni le lero.

Nigba ti iṣẹ ba pari, ti wọn si lọ ṣii fun lilo, yoo jẹ ọkan gboogi nipa imọ sayẹnsi, tẹkinọlọji lorileede Naijiria.
 
A gbọ pe awọn ọdọ yoo maa lo gbọgan naa lati fi kọ nipa imọ ẹrọ ati awọn nnkan loriṣiriṣi bii 'Software engineering, artificial intelligence, machine languages, graphics design, robotics, digital marketing'
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI