Gbajugbaja olukọ ni fasiti Tai Ṣolarin to wa niluu Ijẹbu-Ode, Ọmọwe Balogun Ọlaniran ti foju ba ile ẹjọ lori ẹsun wi pe o fẹẹ fipa ba akẹkọọ kan laṣepọ.
Ọmọwe Ọlaniran ni ọga agba, ẹka ikẹkọọ ẹsin, iyẹn Religious Studies laaarin oṣu kẹwaa si oṣu kọkanla, ọdun 2021.
Wọn ni niṣe lo sọ pe oun fẹẹ ba akẹkọọbinrin kan ti a fi orukọ bo laṣiri laṣepọ, tabi ki ọmọbinrin naa san ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira, lati le fun un ni maaki.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣe kẹta, ọdun ti a wa yii ni ajọ to n gbogun ti iwa ọdaran ti a mọ si Independent Corrupt Practices and other related offences Commission, ICPC foju Ọmọwe Ọlaniran ba ile ẹjọ giga to wa niluu Ijẹbu Ode, ipinlẹ Ogun.
Nibẹ ni wọn ti fi ẹsun kan ṣoṣo to nii ṣe pẹlu iwa jibiti kan an niwaju Onidajọ Ọṣinuga.
Ẹsun ti wọn fi kan an la gbọ pe o tako iwe ofin ọdaran ajọ naa ti abala 8 (1) (a), ọdun 2000.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ ajọ naa, Arabinrin Azuka Ogugua ṣe ṣalaye lọjọ Ẹti, Furiadee to kọja yii, o ni niṣe ni Ọlaniran n dunkooko mọ akẹkọọbinrin naa lati ba a laṣepọ.
O ni bi ko ba le gbe ara rẹ silẹ lati ba a laṣepọ, ko lọ san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira, koun le fun un ni maaki.
A gbọ pe ọmọbinrin naa ko ṣe daadaa ninu idanwo ọkan lara awọn iṣẹ to ṣe, to si kuna ninu awọn iṣẹ naa. Awọn iṣẹ naa EDU 311 ati EDU 312 ni akẹkọọbinrin naa kuna ninu ẹ.
Ogagua sọ pe Ọlaniran loun ko jẹbi niwaju ile ẹjọ, ṣugbọn ti ile ẹjọ sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kọkanla, oṣu karun-un, ọdun yii.
Bakan naa lo jẹ mọ pe ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira ni ile ẹjọ ni ki wọn gba beeli Ọlaniran, pẹlu oniduro meji ọtọọtọ to n gbe nitosi ile ẹjọ naa.
No comments:
Post a Comment