Ẹ ma ṣe fi ọrọ ẹsin tu Naijiria ka o - Gani Adams pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, April 7, 2023

Ẹ ma ṣe fi ọrọ ẹsin tu Naijiria ka o - Gani Adams pariwo sita


Iba Gani Adams to jẹ Aarẹ Ọnakakanfo ilẹ Yoruba, ti pariwo, o si ti parọwa s'awọn araalu lati ṣe fi ọrọ ẹsin da wahala, paapaa ija ẹlẹyamẹya s'orileede Naijiria.
 
Oloye Gani Adams ni gbogbo ohun to ba gba pata lawọn yoo fun un lati ma ṣe jẹ ki aba awọn ẹni ika wa si imuṣẹ rara nipa bi wọn ṣe fẹẹ yẹpẹre Ile-Ifẹ ti i ṣe orisun ilẹ Yoruba.
 
Iba Gani Adams ṣekilọ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, nibi ti wọn ti n ṣayẹyẹ ajọdun Ooṣa Eledumare, eyi to waye ni agbegbe Amuwo Odofin, nipinlẹ Eko. Lakooko to n sọrọ nipa ija ẹsin kan bayii to fẹẹ waye n’Ile-Ifẹ laipẹ yii, ni Iba Gani Adams ti sọ pe ki i ṣe ohun to daa rara bi wọn ṣe fẹẹ dija ẹsin silẹ.
 
O ni ọjọ ti pẹ diẹ sẹyin bayii tawọn ẹlẹsin mejeeji naa ti n gbe papọ, ti ko sija laarin awọn. Iba Gani Adams ni o ṣe waa jẹ akoko yii ti ilẹ Yoruba ṣẹṣẹ fẹẹ maa gbadun ni wọn fẹẹ tun dija miiran silẹ bayii.
 
Bakan naa ni Iba Gani Adams tun rọ awọn ọdọ pe ki wọn ma ṣe lọwọ ninu gbogbo ohun to le daja nla tabi ija ẹsin silẹ, paapaa ju lọ nilẹ Yoruba.
 
O ni ile Ifẹ, orirun ilẹ Yoruba ni, ko yẹ kawọn ọdọ jẹ ki wọn lo wọn fun ohun aburu rara niluu naa.
 
Iba Gani Adams ni awọn orilẹ-ede bii Amẹrika, pẹlu ilẹ China ta a n pe wo loke bayii, ki i ṣe ọrọ ẹsin lo gbe wọn debi ti wọn wa.
 
Siwaju si i, Iba Gani Adams gboṣuba nla fun igbesẹ pataki ti Oba Adeyeye Ogunwusi, Ọọni Ifẹ, gbe lori ọrọ naa, to si pana rẹ ni kia ko too di ohun nla ti apa ko ni i le ka mọ rara.
 
Aarẹ Ọna Kakanfo tun rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ OPC pe ki wọn lo akoko ọdun Eledumare to n lọ lọwọ yii lati tọrọ ohun gbogbo ti wọn ba n fẹ gan-an lọwọ rẹ.

ALAROYE

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI