Baale ile fi ebi pa ọmọ rẹ meji titi ti wọn fi ku n'ipinlẹ Ogun, o tun lọ sinku wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, April 21, 2023

Baale ile fi ebi pa ọmọ rẹ meji titi ti wọn fi ku n'ipinlẹ Ogun, o tun lọ sinku wọn

 
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii lọrọ baba agbalagba kan to ṣeku pa awọn ọmọ rẹ meji ṣi n jẹ fun awọn to gbọ, paapaa awọn mọlẹbi rẹ.
 
Ohun to tiẹ tun n ya ọpọ eeyan lẹnu ni bi baba naa, Gbenga Ogunfadekẹ ko tun ṣe sọ otitọ nipa ibi ti oku awọn ọmọ naa wa titi di asiko yii, ṣugbọn ti ileeṣẹ eto aabo Amọtẹkun ti sọ pe iwadiii ṣi n tẹsiwaju.
 
Gẹgẹ bi atẹjade to wa lati ọwọọ Olori ogun Amọtẹkun Ogun, CP David Akinrẹmi ṣe ṣalaye, iyawo Ogunfadekẹ, Busọla Otuṣẹgun, ni wọn lo ke gbajare, pe ninu ọmọ mẹta toun bi fọkọ oun tẹlẹ yii, o ti pa meji ninu wọn.

Obinrin naa ṣalaye, pe oun ati Gbenga to n ṣiṣẹ babalawo ti pinya bii tọkọ-taya tipẹ. O ni awọn ọmọ mẹta tọjọ ori wọn jẹ mejidinlogun (18), mẹtadinlogun (17) ati mẹrindinlogun (16) loun fi silẹ fun un nigba tawọn ko fẹra awọn mọ.

Busọla sọ pe Gbenga taku nigba naa ni, ko jẹ koun ko awọn ọmọ naa lọ loun ṣe fi wọn silẹ pẹlu rẹ. O ni oun gba Warri lọ, nipinlẹ Delta, nibi toun ti fẹ ọkọ mi-in.

O fi kun un pe oun ko lanfaani lati maa ri awọn ọmọ oun deede lọdọ baba wọn ti wọn wa, ṣugbọn oun maa n beere alaafia wọn lọwọ rẹ daadaa, o si maa n sọ foun pe alaafia ni wọn wa, kinni kan ko ṣe wọn.

Aṣe meji ti ku ninu awọn ọmọ mẹta ọhun toun ko mọ, ọmọ ti ku iya o gbọ nile ni Busọla sọ pe o ṣẹlẹ lọrọ oun.

Nipa bo ṣe pada gbọ iku awọn ọmọ naa, iyawo Gbenga tẹlẹ yii sọ pe ọmọ to kere ju ninu awọn ọmọ oun lo pade ẹnikan to jẹ anti fun un ni Ibiade, nijọba ibilẹ Waterside, nipinlẹ Ogun, ọmọ naa lo si ṣalaye ohun to fa iku awọn ẹgbọn rẹ mejeeji fun obinrin naa to fi dohun tawọn agbofinro pada gbọ.

Ọgbọnjọ oṣu kẹta ọdun 2023 yii ni ọmọ ọdun mẹrindinlogun naa ṣalaye fun anti to pade, pe niṣe ni baba awọn ti awọn mọle kọja oṣu mẹta.

O lo so awọn mọlẹ bi ọbọ sibi tẹnikẹni ko ti le ri awọn rara, bẹẹ ni ko si fun awọn lounjẹ ati omi rara ni.

Iya ajẹkudorogbo yii lọmọ naa sọ pe o pa ẹgbọn oun agba to jẹ ọkunrin, iyẹn Yusuf Ogunfadekẹ, ati ẹgbọn oun obinrin; Dasọla Ogun Fadekẹ.

O ni boun gan-an ko ṣe ba iṣẹlẹ naa rin ki i ṣe agbara oun, aanu loun ri gba lori fi ko oun yọ lọwọ iku ojiji.

Ọmọ to n gbe pẹlu baba rẹ naa fi kun un pe ninu oṣu kẹrin si ikẹfa ọdun 2022 lawọn ẹgbọn oun ku n’Ijẹbu-Ode tawọn n gbe lasiko yẹn. O ni lẹyin iku wọn loun ati baba awọn ṣẹṣẹ ko lọ si Ibiade tọwọ ti waa ba a yii.

Nigba to n ṣalaye ara ẹ fawọn agbofinro lẹyin tọwọ ba a, Gbenga Ogunfadekẹ sọ pe loootọ loun ti awọn ọmọ naa mọle, ṣugbọn oun ko ṣai fun wọn lounjẹ.

O ni iku ti wọn ku ki i ṣe nitori pe oun febi pa wọn. Babalawo naa sọ pe awọn ọmọ ọhun ṣe aarẹ ni, oun si gbe wọn lọ sọsibitu ṣugbọn wọn pada ku.

Lori idi to fi so wọn mọle to si ti wọn mọle, Ogunfadekẹ sọ pe awọn ọmọ naa n jale ni, oun ko si fẹ ki wọn jale mọ loun ṣe ti wọn mọle.

Boya ọrọ rẹ yii ko ba ṣee tẹle bi awọn Amọtẹkun ṣe wi, iyẹn ka ni ileewosan to loun gbe awọn ọmọ naa lọ n’Ijẹbu-Ode ṣee de ni. Ṣugbọn awọn ọsibitu to loun gbe wọn lọ naa ko si lakọsilẹ nibi kankan n’Ijẹbu-Ode, ẹnikẹni ko ri wọn, ko sọsibitu to n jẹ bẹẹ rara.

Bakan naa ni wọn tun ni ko mu awọn lọ sibi to sinku awọn ọmọ ọhun si, irọ lo tun ba de, ofege nilẹ to n wa ninu aworan yii, ẹnikan ko ri oku awọn ọmọ Ogunfadekẹ. Eyi lawọn agbofinro fi sọ pe o ṣee ṣe ki ọkunrin babalawo yii ti lo awọn ọmọ naa fun oogun owo.

Ko si mọlẹbi kan to gbọ nipa iṣẹlẹ naa ninu awọn eeyan Gbenga bi alaye ikọ Amọtẹkun, ohun to ṣe fawọn ọmọ rẹ ati bi wọn ṣe doku pẹlu bo ṣe da sin wọn ko han sẹnikan ninu wọn.

Afi nigba tọrọ ṣẹṣẹ de gbagede wayi, ti wọn mu baba ẹni ọdun marundinlaaadọta (45 years ) naa ṣinkun.

Ni bayii ṣaa, wọn yoo taari rẹ si ẹka to n wadii iwa ọdaran bi eyi nipinlẹ Ogun, lẹyin ibẹ, ile-ẹjọ ni taara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI