Awọn oloro kọju ija s'awọn musulumi n'Ile Ifẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 1, 2023

Awọn oloro kọju ija s'awọn musulumi n'Ile Ifẹ


Niṣe lọrọ di boolọ o yago lọna l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii, nigba ti awọn oniṣẹṣe ti Oloro kọju ija s'awọn ẹlẹsin Musulumi ninu mọṣalaṣi lakoko ti wọn fẹẹ lọ kirun irọlẹ, eyi ti wọn pe ni Salatul Asr.
 
Ohun ti a gbọ ni pe nnkan bi aago mẹrin aabọ irọlẹ, l'awọn Oloro naa lọ digun ba awọn agbaagba ẹsin naa bii Imaamu ati awọn Aafa, ti wọn si ṣe wọn ṣibaṣibo.
 
Mọṣalaṣi ti wọn pe ni Idi Ọmọh to wa lagbegbe Ilare, niluu Ile-Ifẹ, ipinlẹ Ọṣun niṣẹlẹ naa ti waye, gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe ṣalaye.
 
Asiko aawẹ ti iṣẹlẹ naa bọ si la gbọ pe o mu kọrọ ọhun di ariwo nla, nitori pe awọn musulumi to n gba aawẹ Ramadaani to wa nita lasiko yii lawọn Oloro naa deedee lọ kọlu lojiji.
 
Gẹgẹ bi ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe ṣalaye, Ọgbẹni Bashir AbdulAzeez sọ pe
“A fẹẹ kirun irọlẹ, iyẹn Salatul Asr ni. Ibi ti a ti n ṣe aluwala l'awọn Oloro naa ti wa ba wa niwaju ita Mọṣalaṣi. Wọn sọ pe ka kuro nibi ti a wa.

“Ko to di pe a bẹrẹ sii ṣalaye ohunkohun, wọn ti bẹrẹ sii lu Imaamu wa, to fi mọ awọn ọmọ iya wa lọkunrin ati l'obinrin ninu ẹsin Islam. Loju ẹsẹ ni wọn tun ti yawọ inu mọṣalaṣi, ti wọn si ba Kuraani atawọn dukia miran jẹ.”
 
Imaamu Abdul-Lateef Adediran, AbdulWahab ati awọn marun-un miran la gbọ pe wọn farapa yanna-yanna, ti wọn si ti wa ni ọsibitu awọn olukọni ti fasiti Ọbafemi Awolọwọ to wa niluu Ile-Ifẹ.
 
A gbọ pe Ọjọbọ, Tọsidee to kọja yii lawọn Oloro naa n ṣe Oro wọn niluu Ile-Ifẹ, ti wọn si ni kẹnikẹni ma ṣe jade sita.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI