Lojuna lati ni ibaṣepọ to dan mọnran laaarin awọn ọba ilẹ Yoruba, Arujalẹ Ojima tiluu Okelusẹ to wa n’ijọba ibilẹ Ọsẹ, ipinlẹ Ondo, Ọba Oloyede Adeyẹọba Akinghare keji ti ṣabẹwo s’awọn ọba ilẹ Ẹgba niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
Ọba Oloyede lo ṣabẹwo s’awọn ọba ilẹ Ẹgba l’Ọjọru tii ṣe Wẹsidee ati Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii, pẹlu erongba lati kẹkọọ siwaju sii nipa ipo ọba, ati igbe aye ọba.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ile Ọba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan niluu Orile-Ilawọ, Ọba Oluṣẹgun Alexandar Macgregor to wa niluu Abẹokuta ni Ọba Oloyede de si, ko to di pe wọn lọ kaakiri lati b’awọn ọba ilu Ẹgba lalejo.
Ọba Oloyede tun lo anfaani abẹwo ọhun lati de ori oke Olumọ ti wọn fi sọri ilu Abẹokuta, iyẹn ibi to jẹ orirun ilu Ẹgba to wa lagbegbe Ikija.
A gbọ pe aafin Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ ni Ọba Macgregor kọkọ mu Ọba Oloyede lọ, ṣugbọn to ṣeni laanu pe kabiyesi ko nile lakoko naa.
Wọn ni ibi ipade nla kan ni Alake ilẹ Ẹgba lọ nilẹ Amẹrika, ṣugbọn ti awọn aṣoju Alake gba Ọba Oloyede Adeyẹọba lamọran, bẹẹ ni wọn tun gbadura alaafia ati ẹmi gigun lori ipo ọba naa fun un.
AWIKONKO gbọ pe ṣaaju akoko yii ni aajọṣepọ to dan mọnran ti wa laaarin Ọba Oloyede ati Ọba Macgregor, eyi to jẹ ki wiwa rẹ siluu Ẹgba, ipinlẹ Ogun lọ nirọrun.
Ninu ọrọ amọran Ọṣilẹ Oke Ọna Ẹgba, Ọba Adedapọ Adewale Tẹjuoṣo sọ pe lara nnkan to moun bori ọta ni pe oun gba fun Ọlọrun to da oun, eyi ti ko jẹ ki ogun aye bori oun.
O lawọn eeyan ro pe oun ko le lo ọdun meji lori itẹ naa, ṣugbọn nitori Jesu toun gba sinu aye oun, oun lanfaani lati lo ọdun mẹrinlelọgbọn, to si loun yoo ṣi tubọ lo ju bẹẹ lọ.
Kabiyesi gba Ọba Adeyẹọba lamọran lati fi Ọlọrun, iyẹn Jesu ṣe igbẹkẹle rẹ, ko si yago fun awọn oriṣa atọwọda, nitori pe Jesu nikan lo le muu bori ogun, nitori pe ipo ọba kii ṣe ipo teeyan n foju lasan ṣe, bi ko ṣe pe lati wa ninu ẹmi ni gbogbo igba lo ṣe koko.
Nigba toun naa n sọrọ, Olowu tiluu Owu, Ọba Adelọla Saka Matẹmilọla sọ pe iwuri nla lo jẹ foun lati gba Ọba naa lalejo niluu Ẹgba, to si ni lara ohun to ilu naa fi da yatọ ni pe wọn fẹran alejo pupọ.
Oluwo sọ pe ibaṣepọ ati iṣọkan laaarin awọn ọba ilẹ Yoruba ṣe pataki pupọ fun ilọsiwaju, to ni si ni oyinbo alawọ funfun lo da wahala silẹ niluu Ẹgba nigba ti wọn de.
Kabiyesi sọ pe gbogbo eto lo n lọ daadaa niluu Ẹgba, ati pe niṣe ni ilu Ẹgba dabi orileede kan lọtọ ko to di pe awọn oyinbo wa fi ọrọ ẹsin tan wọn jẹ, ti wọn si fi da ọtẹ silẹ laaarin wọn.
O wa pe fun alaafia ati iṣọkan laaarin awọn ọba ilẹ Yoruba to ku, to si ni ki gbogbo wọn ri ara wọn gẹgẹ bi ọmọ iya kan naa ti ko gbọdọ tuka, lati le de ibi ti wọn n foju sọna fun lati de.
Lẹyin eyi la gbọ pe wọn tun lọ si aafin Agura tiluu Gbagura, Ọba Babajide Bakre, nibi ti kabiyesi naa ti fi idunnu rẹ han pe igbesẹ gidi ni ọba naa gbe, ati pe gbogbo ohun to ba wa ni ikawọ oun loun yoo lo lati fi jẹ ki Ọba Adeyẹọba ṣe aṣeyọri.
Ọba Bakre ni lara awọn nnkan to le mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba ilẹ Yoruba ni ki awọn ọba wa ni irẹpọ to loorin, ati pe ki wọn maa gba fun ara wọn ni gbogbo igba.
Siwaju sii ni Ọba Bakre sọ pe lara nnkan to dara ju ni lati fi kekere j’ọba bii ti Ọba Adeyẹọba, nitori pe agbara ọmọde naa yoo jẹ ki ipinnu rẹ tete wa si imuṣẹ.
Arujale Okelusẹ nigba toun naa n sọ pataki idi to fi wa siluu Ẹgba, ṣalaye pe ọmọ ọdun mẹẹdogun loun wa, nigba ti wọn sọ pe oun ni ipo naa kan lọdun 2019, to si lo ko ibẹru bojo sọkan oun.
O ni oun nilo ọgbọn, imọ ati oye, paapaa irẹpọ laaarin oun atawọn ọba ilẹ Yoruba ti wọn jẹ bii baba foun, nitori pe ọna kan ṣoṣo toun le gba lati ṣaṣeyọri niyẹn.
Nibẹ lo ti fi aidunnu rẹ han si b’awọn ọba kan ko ṣe kii gba funra wọn, paapaa ti wọn yoo tun maa fi oju eeyan kekere wo awọn ọba ilu ti wọn ṣẹṣẹ n dagba soke.
O loun ṣetan lati ba ọba to ba n’ọwọ ifẹ soun ṣe papọ, nitori pe ifẹ, alaafia ati iṣọkan Yoruba loun n wa kaakiri.
Lakotan, Ọba Adeyẹọba dupẹ gidigidi lọwọ Ọba Oluṣẹgun Macgregor fun bo ṣe gba a lalejo, to si tun mu oun kaakiri ọdọ awọn ọba alaye ilu Ẹgba, pẹlu ileri wi pe awọn yoo ni ajọṣepọ to gumọ siwaju sii.
Bakan naa lo gbe oriyin nla fun Oba Oluṣẹgun Macgregor fun ọwọ ifẹ to na soun, ati awọn ayipada rere to ti de ba ilu Orile-Ilawọ. Bẹẹ lo kii fun awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke to ti ṣe laaarin ilu naa, ati bo ṣe n ṣeto ironilagbara fawọn eeyan, paapaa ọdọ ati akẹkọọ.
No comments:
Post a Comment