Ọjọ manigbagbe lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii jẹ niluu Oke-Ako, ijọba ibilẹ Ikọle to wa nipinlẹ Ekiti nigba ti wọn sọ pe iji lile gbe orule ile ti ko din ni marunlelọgọrun-un lọ.
Iji lile naa sọ ọpọ awọn onile ati ayalegbe di alainile lori, nitori pe ojiji lo ba wọn.
B'awọn kan ṣe n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn irunmọlẹ lo binu, ti iji lile naa fi ṣọṣẹ, bẹẹ l'awọn kan n sọ pe kii ṣoju lasan, ṣugbọn ti ko tii sẹni to ye.
Nnkan bi aago mẹta ọsan ọjọ naa la gbọ pe iji lile yii bẹrẹ, ko to di pe ojo arọọrọda bẹrẹ.
Yatọ si pe iji naa wo ọpọ ile, wọn lo tun ba awọn ipo ina to wa lagbegbe naa jẹ, eyi to jẹ ki wọn wa ninu okunkun.
Nigba to n ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ naa lọjọ Satide, Abamẹta ana, igbakeji gomina ipinlẹ Ekiti, Moniṣade Afuyẹ kọminu lori iṣẹlẹ naa, to si b'awọn eeyan kẹdun.
Bakan naa ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ igbakeji gomina lori ọrọ iroyin, Victor Ogunje gbe sita, o ni igbakeji gomina naa dupẹ pe iṣẹlẹ ọhun ko mu ẹmi lọ.
O wa fi kun ọrọ rẹ pe ijọba ipinlẹ naa yoo ṣe iranwọ to ba yẹ laipẹ.
Fọto ree;
No comments:
Post a Comment