Aarẹ tuntunt t'awọn ọmọ orileede Naijiria ṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ti lọ fi ẹmi imoore rẹ han si Ọba ilu Ekoo, Ọba Rilwan Akiolu.
Lonii, ọjọ Aiku, Sannde ni Tinubu mu iwe ẹri ti ajọ eleto idibo lorileede Naijiria, INEC gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo lati lọ fi han Ọba Akiolu, Elekoo tiluu Ekoo.
Funra Tinubu lo gbe iroyin naa sita lori ikanni ayelujara ti fesibuuku rẹ, to si jẹ ko di mimọ pe Gomina Babajide Sanwo-Olu wa lara awọn to kọwọrin pẹlu oun lọ si aafin Elekoo to wa lagbegbe Iga-Iduganran.
Fọto ree:
No comments:
Post a Comment