Ṣọọṣi Pentecostal Santuary niluu Ijẹbu Ode fẹẹ ṣayẹyẹ ọdun mẹtadinlọgbọn lara ọtọ, pelu asọtẹlẹ tuntun fun Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, March 3, 2023

Ṣọọṣi Pentecostal Santuary niluu Ijẹbu Ode fẹẹ ṣayẹyẹ ọdun mẹtadinlọgbọn lara ọtọ, pelu asọtẹlẹ tuntun fun Naijiria


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ọkan lara awọn ile ijọsin to gbajumọ daadaa lorileede Naijiria, Pentecostal Sanctuary Bible Ministries to wa niluu Ijẹbu Ode lati ṣayẹyẹ ọdun mẹtadinlọgbọn ti wọn da a silẹ.
 
Yatọ si eyi, wọn tun fẹẹ ṣe ipagọ ṣọọṣi naa, ẹlẹẹkọkanlelogun iru ẹ, eyi ti yoo bẹrẹ lọjọ kẹjọ, oṣu kẹta, ọdun 2023 ti a wa yii.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, oriṣiriṣi eto ni igbimọ alakoso eto ipagọ ati ayẹyẹ naa ti la kalẹ, eyi ti yoo jẹ ki t'ọdun yii yatọ si awọn eyi ti wọn ti n ṣe tẹlẹ.
 
Ninu atẹjade ti Pasitọ Tayọ Owode kọ ranṣẹ s'AWIKONKO lorukọ igbimọ naa, o jẹ ko di mimọ pe akori ayẹyẹ t'ọdun yii ni wọn pe ni DIVINE FRUITFULNESS AND MULTIPLICATION ti wọn yọ ninu bibeli, Jẹnẹsisi ori kinni, ẹsẹ kejidinlọgbọn {Gen. 1vs28}.
 
Eto ọhun ni yoo bẹrẹ pẹlu ipade awọn akọroyin ti yoo waye ninu ijọ naa to wa ni ojule kẹsan, Ararọmi Lane, Odo-Ẹgbọ niluu Ijẹbu Ode, bẹrẹ lati aago mẹwaa aarọ, iyẹ lọjọ kẹjọ, oṣu kẹta, ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI