Ọwọ tẹ 'Olu Maintain', ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 2, 2023

Ọwọ tẹ 'Olu Maintain', ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun l'Abẹokuta


Boroboro bayii ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹfa kan tọwọ ẹṣọ aabo ipinlẹ Ogun, So-Safe Corps tẹ laipẹ yii n ka, nigba ti ọwọ palaba wọn segi.
 
Awọn tọwọ tẹ yii ni iroyin fi to wa leti pe wọn ko niṣẹ meji ti wọn fi n jẹun, to kọja ẹgbẹ okunkun ati idigunjale.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awọn oṣiṣẹ aabo naa ti wọn n ṣiṣẹ ni Ọbasanjọ Hilltop to wa ni Oke-Mọsan, Abẹokuta lo rọwọ to Emmanuel Victor, ẹni ọdun mejilelọgbọn to n gbe lagbegbe Rounder.

Bi ọwọ ṣe tẹ, o jẹ iyalẹnu wi pe wọn ba ọtan ibọn mẹrin ninu baagi to gbe dani, eyi to jẹ ki wọn ṣe iwadii rẹ daadaa, to si jẹwọ pe ibi toun ti n ṣiṣẹ alagbafọ loun ti n ko awọn ọta ibọn naa bọ.
 
Nibẹ lo ti jẹwọ gbogbo awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ, to si darukọ awọ marun-un, pẹlu wi pe o tun mu wọn lọ sibi tọwọ ti tẹ wọn.
 
Victor jẹwọ siwaju pe ogbologboọmọ ẹgbẹ okunkun Aye loun, ati pe ẹnikan to tun jẹ ọlọwọ ọtun oun ni Olumide Abdullah, ẹni t'awọn tun n pe ni 'Maintain'.
 
Awọn miran tọwọ tun tẹ ni; Isiaka Jimọh, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn; Oluwaṣeun Gabriel, ọmọ ogun ọdun ti wọn tun n pe ni Atunbi; Ojeka Samuel, ọmọ ọdun mọkandinlogun; ati Adisa Rasheed, toun naa jẹ ọmọ ọdun mọkandinlogun.
 
Mọruf Yusuf to jẹ agbẹnusọ fun ẹṣọ aabo naa jẹ ko di mimọ pe ọga awọn Sọji Ganzallo ti paṣẹ pe ki wọn ko awọn afurasi ọdaran naa llọ f'awọn ọlọpaa lati tẹsiwaju iwadii wọn.
 
Bakan naa lo fi ye wa pe awọn gba awọn nnkan ija ogun bii Aake mẹta, ada marun-un, sisọọsi mẹrin, ọbẹ kan, tẹsibiu atawọn miran lọwọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI