Ọjọ manigbagbe l'Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii jẹ, nigba ti wọn kede Ọjọgbọn Oluṣọla Babatunde Kẹhinde gẹgẹ bii Giwa fasiti ọgbin, iyẹn Federal University of Agriculture, FUNAAB to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
Ninu ipade igbimọ alaṣẹ fasiti naa, eyi to waye lọjọ keje, oṣu kẹta, ọdun 2023 to a wa yii la gbọ pe wọn ti fẹnu ko lori Ọjọgbọn Oluṣọla Babatunde Kẹhinde gẹgẹ bi Giwa keje fun fasiti ọhun.
AWIKONKO gbọ pe Ọjọgbọ Kẹhinde lo jawe olubori ninu idije yiyan giwa to waye laipẹ yii, ti wọn si lo ṣe daadaa ju awọn akẹgbẹ rẹ mẹrinla yooku ti wọn jọ gba fọọmu lọ.
Alaaji Umar Ahmẹd to jẹ giwa agba ati alaga igbimọ iṣakoso fasiti ọhun nigba to n kede Ọjọgbọn Kẹhinde sọ pe oun nikan lo kun oju oṣuwọn laaarin awọn yooku, to si gba a lamọran lati mu iṣẹ tuntun to ṣẹṣẹ gba naa lokukudun.
Nigba to n fi idunnu rẹ han lori iwe ipe si iṣẹ tuntun naa, Ọjọgbọn Kẹhinde sọ pe iwuri nla lo jẹ foun lati jawe olubori, to si ṣe ileri wi pe gbogbo ọgbọn, imọ ati oye toun ni loun yoo fi mu itẹsiwaju ba fasiti naa.
Bakan naa lo tun fi kun ọrọ rẹ wi pe gbogbo ileri toun ṣe ninu lẹta oun ṣaaju ki wọn to yan oun loun yoo mu wa si imuṣẹ, ati pe ifẹ, iṣọkan ati alaafia fasiti naa jẹ oun logun pupọ, to si loun yoo sa ipa ati akitiyan oun lori ẹ.
Ọmọ bibi ilu Gbagura to wa nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta ni Ọjọgbọn Kẹhinde, ẹni ti wọn bi lọjọ kejelelogun, oṣu kejila, ọdun 1964. O lọ sile ẹkọ girama ti Abẹokuta, iyẹn Abeokuta Grammar School, Idi-Aba, laaarin ọdun 1976 si 1981.
Siwaju sii lo tẹsiwaju ni ile ẹkọ gbogboniṣe ti ipinlẹ Ogun, to ti wa di Moshood Abiola Polytechnic bayii niluu Abẹokuta, nibi to ti kékọọ gbooye Higher School Certificate (HSC).
O tun kẹkọọ gbọye Bachelor and Master of Science Degree ninu imọ ẹkọ Agricultural Biology, bẹẹ lo tun kẹkọọ gboye gẹgẹ bii Doctor of Philosophy (Plant Breeding and Genetics) ni fasiti Ibadan to wa nipinlẹ Ọyọ laaarin ọdun 1987, 1990 ati 1994.
Yatọ si eyi, Ọjọgbọn Kẹhinde di igbakeji olukọni ni fasiti FUNAAB, ẹka ikẹkọọ Plant Breeding and Science Technology, lọdun 1994. Nibẹ lo ti tẹsiwaju ko to kẹkọọ gboye Ọjọgbọn ni ẹka ikẹkọọ kan naa lọjọ kinni, oṣu kẹwaa, ọdun 2007 titi di asiko yii.
Alakoso ti a mọ si Dean, ẹka ikẹkọọ College of Plant Science and Crop Production ni Ọjọgbọn Kẹhinde laaarin ọdun 2009 ati 2011. Lọdun 2021 lo di igbakeji Giwa (Development) fasiti naa, ko to di Giwa-fidihẹ.
Diẹ ree lara awọn iwe ẹri ti Ọjọgbọn Kẹhinde tun ni;
(1) Fellow, Institute of Health and Safety, Canada;
(2) Fellow, Association of Applied Information Management Professionals (FAIMP);
(3) Fellow, Genetics Society of Nigeria;
(4) Member, African Crop Science Society; and
(5) Member, Horticultural Society of Nigeria.
Ọjọgbọn Kẹhinde fẹ iyawo, toun naa tun jẹ Ọjọgbọn, Iyabọde Adekẹmi Kẹhinde, ti Ọlọrun si pese ọmọ mẹta fun wọn.
No comments:
Post a Comment