Boroboro ni gendekunrin ti ẹ n wo oju rẹ yii, Adegboyega Sulaimọn Adesanya n ka, nigba tọwọ palaba rẹ segi nibi to ti lọ ji ẹrọ amunawa jẹnẹretọ gbe.
Nnkan bi aago marun aabọ irọlẹ, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii la gbọ pe ọwọ ẹṣọ aabo tijọba ipinlẹ Ogun, iyẹn So-Safe Corps lo tẹ Sulaimọn, lẹyin olobo to ta wọn.
Adugbo Adelaja to wa lopopona Ondo, ijọba ibilẹ Ijẹbu-Ode ni Sulaimọn ti lọ ji jẹnẹretọ meji to jẹ Okayama ati Elepaq gbe.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun ẹṣọ aabo naa, Mọruf Yusuf ṣe ṣalaye, o ni ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin ni Sulaimọn lọ ji adiẹ gbe lagbegbe Idomowo, Ijẹbu-Ode, to si na papa bora.
Yusuf ni ọga awọn, Sọji Ganzallo ti paṣẹ pe ki wọn lọ fa ọmọkunrin naa le awọn ọlọpaa Ọbalende lọwọ fun itẹsiwaju iwadii.
No comments:
Post a Comment