O ti wa ninu akọsilẹ wi pe Tinubu maa di aarẹ Naijiria, iṣẹ Ọlọrun ni - Ọba Eselu sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 2, 2023

O ti wa ninu akọsilẹ wi pe Tinubu maa di aarẹ Naijiria, iṣẹ Ọlọrun ni - Ọba Eselu sọrọ


Eselu tiluu Eselu nijọba ibilẹ Ariwa Yewa, ipinlẹ Ogun, Ọba Akintunde Akinyẹmi ti sọ pe bi oludije s'ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Bọla Ahmẹd Tinubu ṣe jawe olubori ninu eto idibo to waye lopin ọsẹ to kọja yii kii ṣe erongba eniyan, bi ko ṣe iṣẹ ati akọsilẹ Ọlọrun.

Ọba Akintunde lo sọrọ naa laaarọ oni, Ọjọwọ, Tọsidee, lakoko to n gboriyin fun Tinubu lori iṣẹ nla to ṣe lati de ipo aarẹ, to si ni ọkunrin takuntakun ni.

Kabiyesi naa sọ pe bo tilẹ jẹ pe oriṣiriṣi ọrọ ati asọtẹlẹ lawọn woli eke ti sọ, ṣugbọn ti Ọlọrun pada jẹri ara rẹ lati gbe Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC naa de ipo.

Ninu ọrọ rẹ, kabiyesi sọ pe;

"Mo fi asiko yii ki Aarẹ tuntun ti a ṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu, mo si tun fi asiko yii ki gomina wa, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ku oriire ati gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun wi pe a ti dibo, ibo wa si ti f'ẹsẹ mulẹ lati dibo fun Bọla Ahmẹd Tinubu.

"Gbogbo asiko ti a wa yii, ẹyin naa ti n gbọ lori ayelujara kaakiri nipa awọn Wolii eke, awọn wolii Baali. Onikaluku ti n sọ nnkan to wu. Ṣugbọn a ni lati kọkọ gboriyin fun Bọla Ahmẹd Tinubu wi pe o ja takuntakun, o ja bi ọkunrin lati debẹ, nitori pe lati du ipo agbara, kii ṣe kekere.

"Bibeli si sọ pe 'ero yin kii ṣe ero mi, bẹẹ ni ero mi kii ṣe ero yin'. Ọlọrun lo sọ bẹẹ. Ọna Ọlọrun yatọ si ọna ti wa, bẹẹ ni Ọlọrun ti wa yatọ si ọna Ọlọrun. O ti wa ninu akọsilẹ wi pe Aṣiwaju maa di aarẹ, iṣẹ Ọlọrun ni, ẹ ma tu wo.

"Gbogbo ohun to yẹ ka ṣe nisinyi ni pe ka rọgbayi aarẹ tuntun ka, gbogbo ohun to kọ silẹ wi pe o fẹẹ ṣe, iṣẹ ti dele bayii, iṣẹ si ti ya, ko si aaye ẹjọ wiwi mọ, iṣẹ ya, iṣẹ ya, gẹgẹ bi orin ogo ipinlẹ Ogun to sọ pe 'Iṣẹ Ya'.

"Ẹ jẹ ka gbagbe nipa ọrọ ibo, ọrọ ibo ti kọja, ẹni to ba ni kurujẹ, ko gba ile ẹjọ lọ. Ẹ jẹ ki awa tiẹ kọkọ gbe Aṣiwaju sori ila ere ije, ko si bẹrẹ sii ṣiṣẹ lọ. A ni lati ṣe ilu yii, ko dara fun wa lati gbe. Ka ṣe ilu yii fun awọn ọmọ wa ti a ti bi, ati awọn ti a ko tii bi.

"Fun idi eyi, mo rọ gbogbo pe, ẹ jẹ ka rọgba yii ka, ka si fun un ni gbogbo erongba rere ti a ba ni. Ka si gba a lamọran, ti gbogbo ogo Naijiria yoo si pada. Naijiria to n ṣẹjẹ, kii ṣe ẹjẹ wi pe a n jagun lọwọ, ṣugbọn o n ṣẹjẹ wi pe awọn eeyan n jiya, o n ṣẹjẹ wi pe awọn eeyan ko le jẹun ẹẹmẹta lojumọ mọ.

"Ni idi eyi, ẹjẹ ibi lo n ṣẹlẹ ni Naijiria, kii ṣe ẹjẹ to wa lara wa. Inu wa si dun wi pe ẹni ti a n sọ yii, ajanaku kuro ninu mo ri n nnkan firi ni, ti a ba sọ pe a ri Eerin, ka sọ pe a ri Eerin lọrọ Aṣiwaju. O ti ya o, iṣẹ ti ya. Ẹ ṣeun"

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI