Iyalẹnu lọrọ ọmọ ikoko kan ti wọn lo jabọ sinu koto kekere kan niluu Ijẹbu Ode ṣi n jẹ titi di asiko yii, ti wọn si ni ọmọ naa gbabẹ sọda sọrun alakeji.
Ọjọbọ tii ṣe Tọside to kọja yii la gbọ pe ọmọ naa jabọ sinu koto ti omi n da si, nibi to ti n ra koro kaakiri.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, agbegbe kan ti wọn n pe ni Sabo niṣẹlẹ ọhun ti waye.
Wọn ni iya ọmọ naa lo n ṣiṣẹ nileeṣẹ kan ti wọn ti n fọ aṣọ lagbegbe ọhun. A gbọ pe iya ọmọ naa gbe ọmọ yii silẹ lati sare ṣiṣẹ kan to wa lọwọ ẹ.
Ki oloju si to o ṣẹ ẹ, wọn ni ọmọ naa ti ra koro, o si ti lọ jabọ sinu koto ọhun ti wọn sọ pe ibẹ ni gbogbo omi ti wọn n lo da sii.
A gbọ pe ko pẹ rara ti iya ọmọ yii fi bẹrẹ sii wa a lati gbe e mọra, ti ko si rii, eyi to mu ko pariwo sita.
Lẹyin ọpọ wakati ni wọn lawọn kan ṣalabapade oku ẹ ninu koto ọhun, ko to di pe wọn gbe e jade.
Wọn tiẹ lawọn kan sare gbe e lọ si ọsibitu boya wọn ṣi le doola ẹmi ẹ, ṣugbọn ti wọn ni aṣọ ko bọmọyẹ mọ, ọmọ naa gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
No comments:
Post a Comment