Ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko to wa lagbegbe Ikẹja l'Ọjọbọ, Tọside, ọsẹ yii ti da ẹjọ iku fun awọn ọrẹ mẹrin kan lori ẹsun ijinigbe ti wọn fi kan wọn. Obinrin kan ti wọn pe ni Gloria Emole ni ile ẹjọ sọ pe awọn mẹrẹẹrin jigbe.
Victor Chukwunonso, Ifeanyi Maduaka, Obinna Nwankwo ati Richard Nwabueze l'awọn mẹrin naa ti Onidajọ Lateef Lawal-Akapo da ẹjọ iku fun l'Ekoo.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, nnkan bii aago mẹjọ aabọ aarọ, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 2012 ni wọn sọ pe awọn mẹrẹẹrin ji Gloria gbe, ṣugbọn ti ọwọ pada tẹ wọn
Ọjọ kẹtala, oṣu keje, ọdun 2013 ni wọn kọkọ foju wọn ba ile ẹjọ, ti ile ẹjọ si paṣẹ pe ki wọn ṣi wa latimọle, lori ẹsun mẹta ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu idigunjale ati ijinigbe.
Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni wọn sọ pe o tako ofin ọdaran ti abala 297, 285 (2) a, ati 291, t'ọdun 2015.
Ọmọwe Babajide Martins to jẹ alakoso Public Prosecution, sọ fun ile ẹjọ wi pe asiko ti Gloria fẹẹ jade kuro nile to n gbe lojule keje, adugbo Unity, Ogudu GRA ni wọn jiigbe.
Babajide sọ pe ọjọ kejilelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2012 ni wọn fi obinrin naa silẹ, lẹyin ti wọn ti gba owo riba ẹgbẹrun lọna aadọrin owo dọla lọwọ awọn eeyan ẹ.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Lateef Lawal-Akapo paṣẹ pe ki awọn mẹrẹẹrin lọ fi ẹwọn ọdun mẹwaa-mẹwaa gbara lori ẹsun akọkọ ti igbimọ papọ; idajọ iku lori ẹsun keji ti idigunjale, ati ẹwọn ọdun mọkanlelogun lori ẹsun kẹta ti ijinigbe.
No comments:
Post a Comment